Jose Antonio Reyes: Agbábọ́ọ́lù Arsenal nígbà kan rí kú ní ẹni ọdún márùndínlógójì

Jose Antonio Reyes Image copyright PA
Àkọlé àwòrán Reyes wa lara ikọ Arsenal to ṣegun awọn agbọọlu to ku lati gba ife ẹyẹ Premier League ni ọdun 2003 si 2004

Jose Antonio Reyes to gba bóólu fun Arsenal nigba kan ri ti ku ninu ijamba ọkọ kan ni ẹni ọdun marundinlogoji.

Ẹgbẹ agbabọọlu Sevilla ti orilẹ-ede Spain sọ lori Twitter pe ibanujẹ lo jẹ fun wọn lati kede iroyin laabi naa.

Agbabọọlu ọmọ orilẹ-ede Spain naa darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ni oṣu kinni, ọdun 2004 to si wa lara ikọ ti o ṣegun awọn agbọọlu to ku lati gba ife ẹyẹ Premier League ni ọdun 2003 si 2004.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOndo: Dejí sun ọmọ méje àtagbalagba meji mọ́lé nítorí pé ó ń bínú

Arsenal ti fi ibanujẹ wọn han lori iroyin iku Reyes, bẹẹ si ni Thierry Henry ti oun ati Reyes gba bọọlu fun Arsenal laarin ọdun 2004 si 2007 ti gbori yin fun oloogbe naa.

Ẹgbẹ agbabọọlu Extremadura ni Reyes wa ki o to di oloogbe.

Ẹgbẹ agbabọọlu naa ti ba awọn ẹbi ati ọrẹ Reyes kẹdun lori Twitter.

Ni ọdun to kọja, iroyin ni Reyes yoo pada si Arsenal gẹgẹ bii akọnimọọgba labẹ Unai Emery to jẹ ọga rẹ nigba to wa ni Sevilla.

Àwọn ìròyin mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí: