Nigeria Security Tracker: Ọ̀pọ̀ ọmọ Naijiria ti kú sí rògbòdìyàn ó n ṣẹlẹ̀

Obinrin kan ka ọwọ lori o n sunkun Image copyright AFP/Getty Images
Àkọlé àwòrán Ipaniyan kaakiri Naijiria ti sọ ọpọ sinu ibanujẹ

Iwadii ajọ orilẹ-ede Amerika kan ló fidi ẹ mulẹ pé ọpọ ẹ̀mí ti sọnu ni Naijiria.

Iwadii naa ni awọn to ku ninu oriṣiriṣi rogbodiyan ni orilẹ-ede yii ni lati ọdun mẹrin sẹyin din diẹ ni ẹgbẹrun mẹrindinlọgbọn.

Iwadii naa to da lori iṣẹ ẹka ajọ lori ọ̀rọ̀ aabo ni Naijiria (Nigeria Security Tracker) ni awọn wọnyii ni Boko Haram ati awọn daradaran pa pẹlu awọn ti ikọ ologun Naijiria pa laitọ nigba ti wọn n koju igbesunmọmi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAabo to peye gbọdọ wa fawọn olutọju alaisan

Laarin oṣu kẹfa, ọdun 2015 si oṣu karun un, ọdun 2019 ni wọn fi ṣe afojusun iṣẹ iwadii naa.

Ipinlẹ Borno lo ko eyi to ju ninu awọn iku wọn yii nibi ti ẹ̀mí eniyan to ju ẹgbẹrun mẹsan an (9,303) ti lọ, Zamfara (1,963) ati Adamawa (1,529) lo tẹ lee.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Eto aabo to peye ti jẹ ipenija nla fun orilẹede Naijiria

Ipinlẹ Jigawa lo ni iku to kere ju pẹlu eniyan meje. Ipinlẹ Eko gan an ni ju ọọdunrun eniyan lọ (337).

Iwadii naa ni laarin ọdun mẹta yii, ni awọn alakatakiti ẹsin Islam Boko Haram ti pa eniyan 5,598, ti ija awọn daradaran si pa eniyan to din diẹ ni ẹgbẹrun marun un (4,917).

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionGómìnà Zamfara kò lágbára ní tòtọ́ọ́ lórí ọ̀rọ̀ ààbò- amòfin

Atẹjade ajọ naa ni awọn agbofinro naa pa ju ẹgbẹrun mẹrin eniyan lọ (4,068) laarin ọdun mẹrin yii,

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOdumakin sọrọ lori Fulani darandaran