BBC Africa Eye: Akọroyin fẹ ìdí àwọn oníṣẹ́ ibi ọmọ ogun síta
Iwadii yii bí igbesẹ akọni loriṣiiriṣii káàkiri agbaye.
Iṣẹ akọroyin ti yatọ si ti tẹlẹ, o ti mu iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ dani lasiko yii fun idande awọn eniyan agbaye.
- Day 18: Ṣé o fẹ́ mọ òtítọ́ nínu ọ̀rọ̀ ìpolongo àwọn oludije sípò aarẹ Naijiria? #BBCElection2019.
- Kí ló ń pa àwọn ọkùnrin lọ́wọọ̀wọ́ ní Kenya?
- 'Ọmọ Naijiria 25,794 ló kú sí rògbòdìyàn láàrin ọdún mẹ́rin'
- SARS fi ìyà jẹ àwọn akẹ́ẹ̀kọ́ fásitì Akungba
- A kò lè gba àwọn jandùkú Fulani láàyé nílẹ̀ Yoruba -Awọn gómínà
Loṣu keje, ọdun 2018 ni fidio obinrin meji ti wọn ni Boko Haram pa ati awọn ọmọde meji n tan kale lori ayelujara.
Awọn Boko Haram ti wọn jẹ alakatakiti ẹsin Islam ni awọn orilẹ-ede Naijiria, Cameroon, Nijer ati Chad n ba finra gẹgẹ bii agbesunmọmi lasiko yii.
Oriṣiriṣi fidio ni wọn ti fi sita lati fi ṣafihan awọn iṣẹ ibi ti wọn n ni awọn n ṣe fawọn ara ilu ni agbegbe yii.
Eyi lo n ṣokunfa ọpọlọpọ iṣẹ ibi lọwọ oniruuru eniyan lawọn ẹkun yii.
Kete ti fidio yii jade lawọn eniyan ti ni ko ṣẹyin awọn ọmọ ogun Cameroon ṣugbọn ijọba wọn ni irọ ni.
Lẹyin eyi ni awọn akọroyin BBC Africa Eye kan bẹrẹ iṣẹ iwadii ni kikun lori fidio naa lati mọ ohun to ṣẹlẹ nitootọ.
Lẹyin iṣẹ ọpọlọ pẹlu oòrùn, ibudo ti awọn oke to han ninu fọnran naa wa, oju ọjọ, aworan ibọn, ati lilo ikanni ayelujara ni aṣiri tu sita.
Aṣiri to tu yii lo yi ọrọ ijọba Cameroon pada lori awọn oniṣẹ ibi wọnyii.
Esi iwadii Africa Eye ló jẹ ki gbogbo agbaye dide si iranlọwọ Cameroon lati gbogun ti awọn agbesunmọmi atawọn oniṣẹ ibi.
Aliaume Leroy, Benjamin Strick atawọn mii ni Africa Eye niwadii wọn fihan pe iṣẹ akọroyin le gba odindin orilẹ-ede silẹ ki wọn si tu aṣiri awọn oniṣẹ ibi.
IKILỌ: FIDIO YII NI OUN TO BA NI LẸRU