Ladoja
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Rashidi Ladoja: Nígbà tí Ajimobi fìdí rẹmi ló ṣẹ̀ṣẹ̀ yan àwọn akọ̀wé

Gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ ri Oloye Rashidi Ladoja ni nigbà tí Ajimobi ń lọ ló ṣẹ̀ṣẹ̀ kó àwọn akọwe tuntun jade fun ifẹ inu ara rẹ.

O sọ eyi latari awọn igbesẹ tuntun eyi ti gomina tuntun Seyi Makinde n gbe ninu iṣejọba rẹ ni idahun si bi gomina ana Ajimoba ṣe se nigba tirẹ naa.

Gẹgẹ bi ọpọlọpọ ṣe n sọ pe o ti ya Seyi ju lati maa gbe awọn igbesẹ kọọkan, Oloye Ladoja sọ pe Ajimobi to lọ lo pẹ ju lati gbe igbesẹ kii ṣe pe o ya Seyi.

Ibeere to beere ni wi pe "ṣe Ajimobi fẹ ṣe ojúṣáájú ni àbí báwo ni?".

"Bí Ajimobi bá dẹ pánpẹ́ sílẹ̀ fún Seyi Makinde, ṣe o fẹ ko maa ba a lọ bẹẹ ko ko si i?".

Oloye Ladoja ni gẹgẹ bii gomina to n kogba wọle lọ, o yẹ ki Ajimobi fi gbogbo iṣẹ pataki to n ṣe han Seyi Makinde ni.