El Rufai: Òfin má wàásù ìpínlẹ̀ Kaduna ti ń gba àpérò

Image copyright @El Rufai
Àkọlé àwòrán Ọrọ ariwo iwaasu ni Kaduna n gba ero tuntun

Ipinlẹ Kaduna gbe ofin kalẹ to n mojuto bi awọn olori ẹlẹsin gbogbo ṣe lee waasu.

Ofin yii ni ọpọlọpọ ti sọ pe ko le fidimulẹ tó nitori pe ẹlẹ́sìn ni awọn eniyan ilẹ̀ Adulawọ lapapọ.

Awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin nipinlẹ Kaduna lo ṣagbekalẹ ofin naa lati ọdun 1984 ni eyi ti ijọba Gomina El Rufai n ṣe atunṣe si ọna ti yoo gba fi mulẹ sii.

Sheikh Dahiru Maraya to jẹ oniwaasu agba ninu ẹsin Islam ni Kaduna sọ fun BBC pé ofin naa ṣe lodi si ẹtọ ọmọniyan Naijiria ninu iwe ofin ilẹ wa.

Aafa nla oniwaasu naa ni bakan naa ni ofin yii ko ba ilana Islam mu rara.

O ṣalaye pe Anabi Mohammed (SAW) so pé: ki a fi ọrọ naa jiṣẹ lati ọdọ ẹnikan si ikeji ni.

Ati pe oun ko fara mọ ofin aṣẹ gbigba koo too lee waasu naa rara.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Bukola Saraki ni adari wa' - Razaq Atunwa, Kwara

Awọn ajọ ọmọlẹyin Jesu ni Kaduna ti a mọ si Christian Association of Nigeria (CAN) naa ko ṣai fi ero tiwọn han lori koko yii.

Dokita Sunday Ibrahim to jẹ akọwe ẹgbẹ naa nipinlẹ Kaduna ṣalaye fun BBC pé awọn ti gbe igbesẹ to yẹ lori ofin naa.

O ni awọn ti ṣalaye fun ijọba pé ijọ Olorun kọọkan lo ti ṣagbekalẹ ilana ofin ti wọn n tẹle fun alaafia awujọ ti wọn wa koda ki wọn to ṣeto iwaasu.

O ni ko ni ṣeeṣe ki wọn ṣẹṣẹ lọ maa gba aṣẹ fun iwaasu kọọkan ti wọn ba fẹ ṣe fun ẹnikọọkan lawujọ.

Ijọba ipinlẹ Kaduna to ṣagbekalẹ ofin yii ni awọn eeyan n ṣi ofin naa tumọ ni.

O ni ọpọ ninu awọn to n bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu ofin naa ni ko ni imọ kikun nipa rẹ ni.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption#Sweetsweetcodeine: Ẹ wo bí ìròyìn BBC nípa oògùn ikọ́ Codeine ṣe ń tún ayé tó ti bàjẹ́ ṣe

Ijọba ipinlẹ Kaduna ni awọn ṣagbekalẹ ilana ofin naa kii ṣe lati fi da rugudu silẹ ni Kaduna rara bikoṣe lati yonbo alaafia laarin awọn olugbe ipinlẹ ọhun.

Ipinlẹ Kaduna jẹ ọkan lara awọn ipinlẹ Naijiria ti ija ẹsin ati ija ẹlẹyamẹya ti wọpọ julọ.

Ọpọlọpọ ẹ̀mí ati dukia lo dẹ ti sọnu sinu irufẹ ija ẹsin yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOmar Al-Bashir ti wọ́n gbajọba lọ́wọ́ ẹ ló di wàhálà