Homosexualism: Ofin ti f'àyè gba ìbálòpọ̀ Akọs'akọ, Abos'abo ní Botswana

Ibaṣepọ abo s'abo Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ibaṣepọ abo s'abo

Kii ṣe ẹṣẹ ki ọkunrin ati ọkunrin tabi obinrin si obinrin maa jọ lo pọ ni Botswana, "Ìbálòpọ̀ ọkùnrin sí ọkùnrin kò lòdì s'ofin".

Ile ẹjọ ti paṣẹ pe kii ṣe itapa si ofin mọ ki ọkunrin ati ọkunrin tabi obinrin ati obinrin maa bara wọ lo pọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBisi Alimi: Ìyà mi rò pé n kò leè ṣe ni àmọ́ n kò ní ìfẹ́ abo ni mo ṣe fẹ́ akọ

Ṣe ni orilẹede naa kọ ofin to sọ pe ki wọn mu ẹni to ba n ṣe ibalopọ akọs'akọ tabi abos'abo ko si lọ ẹwọn ọdun meje eyi ti wọn ni bo ri labẹ ofin tẹlẹ niyii.

Igbesẹ tuntun yii ti ile ẹjọ Botswana gbe waye lẹyin ti orilẹede Kenya ni awọn ko ni yi ofin tiwọn pada lati jẹ ki ibalopọ akọs'abo ba ofin mu.

Adajọ mẹta lo jọ fẹnuko lati sọ ọdi ofin pe ki wọn fi aaye gba. Adajọ Michael tilẹ sọ wi pe ofin ti tẹlẹ ti ko fi aaye gba a n gbe lẹyin apa kan ni.

Kí ló mú kí àyájọ́ June 12 ṣe pàtàkì ní Nàìjíríà

Ta ni Femi Gbajabiamila tó di Olórí tuntun nílé Asojú-sòfin Nàìjíríà?

Lati ọdun 1965 ni ofin to lodi si ibalopọ akọs'akọ laye igba ti awọn oyinbo amunisin gbe e wa si orilẹede wọn.

Ṣugbọn ni ti eleyi, akẹkọọ kan lo gbe lọ si ile ẹjọ pẹlu alaye pe aye ati ilu gan ti yi pada ti ọpọlọpọ si ti f'ofin gba a kaakiri agbaye. ‘Lóòótọ́ ni ọ̀jọ̀gbọ́n fẹ́ bá mi lòpọ̀’

Awọn ajafẹtọ naa gba ipinu yii wọle ti wọn si juwe rẹ bi igbesẹ pataki lati ni ẹtọọ akọs'akọ nilẹ adulawọ.

Lo ba di ofin lorilẹede Botswana!