'Òbí mi kú nígbà ti mo wà lọ́mọ́ ọdún kan'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Child Labour: Òbí mi kú nígbà ti mo wà lọ́mọ́ ọdún kan'

Emi ati ọrẹ mi la jọ n tọrọ owó fún ìyá àgbà -ọmọde

Fifi ọmọde ṣowo wọpọ ni ilẹ Afrika ṣugbọn tilẹ Naijiria lo pọ ju.

BBC Yoruba jade lọ ṣiṣẹ iwadii nipa ọrọ yii ni eyi ti o ti hande pe ko dun mọ awọn ọmọ ninu.

Ajọ iṣọkan agbaye to n risi ọrọ ọmọde ni agbaye UNICEF ni orilẹ-ede Naijiria lo ni ọmọde ti ko lọ sile iwe ti pọju lagbaye.

BBC ba ọmọde kan ti o sọrọ lori iriri rẹ bi oun ṣe n tọrọ owo.

O ni owo ti oun ba tọrọ yii ni oun ati iya agba maa jọ fi n jẹun.

O ni mẹnuba bi oun ṣe fẹ ko sọwọ oniṣekuṣe nigba kan.