Dino: Àwòrán Omo Agege tí Dino fi síta ń fa àríyànjiyàn

Dino fi aworan Omo Agege sita Image copyright @OvieOmoAgege

Sẹnetọ Dino Melaye ti n gba ọpọlọpọ idahun si aworan ati ọ̀rọ̀ to fi sita nipa Sẹnetọ Omo Agege.

Dino to n ṣoju ẹkun idibo Iwọ Oorun ipinlẹ Kogi nile igbimọ aṣofin agba sọ oko ọrọ si Omo Agege to jẹ igbakeji adari ile aṣofin agba.

Loju opo Instagram ni Dino ti fi aworan ati ọrọ to pe akọle rẹ ni "nigba to ba n ba ole aji ọpa aṣẹ ṣiṣẹ".

Lo ba fi aworan ibi ti Sẹnetọ Omo Agege ti n jade bọ ti yoo si gba ọna ibi ti akọwe ile ti gbe ọpa aṣẹ dání.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLadoja

O kọ ọ̀rọ ikilọ pé ki akọwe "fi ọwọ mejeeji rẹ gba ọpa aṣẹ mu daadaa o, mi o fọkan tan Omo Agege ole yii o".

Lo ba tun kọ esi latẹ́nu akọwe ile pe "Haha Ọga, ẹ ma ṣeyọnu, mo ti di i mu daadaa".

Eyi ti wu ọpọlọpọ ọrọ sita latọdọ awọn ọmọ Naijiria.

Bi awọn kan ṣe ni Dino ko bọwọ fawọn to wa nipo, ti awọn kan n gbe lẹyin ọrọ rẹ, bẹ lawọn miiran n sọ pe

Iru iwa bẹ ta abuku si i gẹgẹ bi aṣofin agba Naijiria.