Apapa Accident: Ọ̀ga RRS ní kò sí ẹ̀mí tó nù lẹ̀yìn ti agolo akẹ́rù wó lu ọkọ̀

Apapa Image copyright @chammyashy
Àkọlé àwòrán Apapa

Ọga ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n koju iṣẹlẹ oju popo (RRS) Tunde Disu ti ni agolo akẹru nla to wo lu ọpọlọpọ ọkọ ni agbegbe Tin Can Island, Apapa ni ipinlẹ Eko ni pe ajọ LASEMA ko pa ẹnikankan.

Disu ti fi ye wa wipe loru ọganjọ ni ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Eko, LASEMA ti gbe agolo naa

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLadoja

Loju opo Twitter, igbakeji kọmisọna ọlọpaa Tunji Disu fi fọnran bi iṣẹ ṣe n lọ sita to si ni wọn ti ri agola nla ẹru naa gbe kuro.

Ko to di akoko yii ni awọn oniroyin ti n sọ pe ko daju boya ẹmi kankan ba iṣẹlẹ naa rin ṣugbọn pe awọn ọkọ naa bajẹ yanna yanna.

Ọjọ abamẹta ọjọ ikẹẹdogun oṣu kẹfa ni iṣẹlẹ yii ṣẹ ti awọn ọmọ Naijiria to ṣoju wn si ti sare ke si ijọba lati tara ṣaṣa si i.

Ẹwẹ, DCP Tunji Disu sọ loju opo Twitter rẹ pe ko si eniyan kankan labẹ ẹru tabi awọn ọkọ naa.

Ọpọlọpọ ọkọ nla pọ kaakiri Apapa nitori ibudokọ oju omi to pọ si agbegbe naa.

Lati mu adinku ba igbokegbodo ọkọ, ijọba apapọ ṣẹṣẹ paṣẹ ki wọn ko gbogbo ohun to n mu ki agbegbe naa ri rudurudu kuro ni.

Fun eyi, aarẹ gbe igbimọ amusẹ ya kan silẹ lati ri mimu u ṣẹ ni kanmọ kanmọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionafin pupa

Related Topics