RRS: Ọwọ́ tẹ olè tó gbé òrùka ìgbéyàwó obìnrin kan mì ní Eko

Taofeek Adebayo ati Toheeb Tijani Image copyright RRS
Àkọlé àwòrán RRS mu Taofeek Adebayo ati Toheeb Tijani ni Oshodi

Ọwọ ọlọpaa ti ba ole oju popo kan ti wọn fẹsun kan wi pe o gbe oruka igbeyawo arabinrin kan mii lẹyin to fi ibọn gba a lọwọ rẹ ni ọjọ Ẹti.

Agbẹnusọ ẹka RRS sọ ninu atẹjade kan wipe ọwọ tẹ afẹsun kan naa nigba ti wọn ko awọn janduku ti o n ja awọn eniyan lole ni popo ni agbegbe Oshodi ati CMS nilu Eko ni ọjọ naa.

Afẹsun kan Taofeek Adebayo ẹni ọdun mọkandinlogun ati ojugba rẹ Toheeb Tijani ọmọ ogun ọdun ni a gbọ wi pe wọn ja obinrin meji ni ole ni Oshodi ti wọn si gba yẹti ati oruka oni goolu lọwọ wọn.

Awọn obinrin naa ni awọn afẹsun kan ọhun lọ ba awọn obinrin yii ninu ọkọ ti wọn wa ti wọn si bẹ wọn ki wọn fun awọn ni owo ti wọn le fi jẹun. Ọkan ninu awọn obinrin naa ni oun na ọgọrun naira si wọn, ṣugbọn wọn kọ jalẹ.

A gbọ wi pe Adebayo dahun pe "Eleyi kii ṣe owo ti wa." Ṣugbọn nigba ti ọkan lara awọn obinrin naa ni ko si owo lọwọ awọn, ọkan ninu awọn afẹsun kan naa fa eti ọkan lara awọn obinrin naa lojiji lati bọ yẹti eti rẹ.

Obinrin naa ni awọn afẹsunkan naa ni awọn yoo pa wọn ti wọn ko ba fun awọn lowo. Lẹyin naa ni wọn fi tipatipa bọ oruka ọwọ ọkan lara wọn ti Adebayo si gbe e mi loju wọn.

RRS sọ pe nigba ti ọwọ awọn tẹ Adebayo pẹlu akẹgbẹ rẹ, Tijani, o jẹwọ wi pe ootọ ni wi pe oun lo gbe oruka naa mi.

O ni oun pada pọ oruka ọhun ti oun si fun ikẹta wọn ti orukọ rẹ n jẹ Young Boy, eyi to sa lọ nigba ti ọlọpaa n le wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBBC Africa Eye: Akọroyin fẹ ìdí àwọn oníṣẹ́ ibi ọmọ ogun síta

RRS ni awọn ti n wa Tijani fun igba pipẹ lori ẹsun pe o ja ẹrọ ilewọ lọwọ eniyan kan loju popo.

Kọmisana ọlọpaa ni Ipinlẹ Eko, Muazu Zubairu ti ni wọn ti fa awọn afẹsunkan naa le ọwọ agọ ọlọpaa to wa ni Makinde, Oshodi ati ẹka to n ṣe iwadii ẹsun ole.

Àwọn ìròyìn mìírànm tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí: