Sarri: Ìbéérè márùn ùn yìí ni Chelsea ní láti dáhùn

Akonimọọgba Chelsea to lọ Maurizio Sarri nigba ti wọn gba ife ẹyẹ Europa League Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Maurizio Sarri nigba ti wọn gba ife ẹyẹ Europa League

Bi Maurizio Sarri ṣe fi Chelsea silẹ lọ Juventus, ẹgbẹ agbabọọlu naa n ti n wa akọnimọọgba kejila ti ṣe akoso lati igba ti Roman Abramovich ti ra Chelsea.

Meta ninu awọn mọkanla to lọ lo jẹ fidihẹ ni wọn, pẹlu Guus Hidink, to was ni Chelsea fun ifẹsẹwọnṣẹ mẹtadinlọgbọn.

Lati ọdun 2004, Chelsea ko ti i ni ju saa kan ṣoṣo ninu eyi ti wọn ko jawe olubori tabi gbe ipokeji tabi wara lara awọn mẹrin iwaju ni Yuroopu. Ẹẹmarun nikan lati ọdun naa ni wọn ko gba nkankan lọ ile.

Nitori naa lo ṣe pọn dandan lati beere oun ti Chelsea n fẹ gan.

Ta ni Chelsea le doju kọ?

Fun gbogo iṣoro ti awọn akọnimọọgba Chelsea maa n doju kọ, awọn ti yoo fẹ tẹ ori si iṣẹ naa yoo pọ.

Frank Lampard to n tukọ Derby County lo jọ pe ade naa yoo ṣi mọ lori.

Igba to wa ni Chelsea, o gba ife ẹyẹ mọkanla ọtọtọ laarin ọdun mẹtala to lo ni ẹgbẹ akọnimọọgba naa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Lampard

Ni Derby, o tun ba akẹgbẹ rẹ nigba kan ri Jody Morris pade. Morris gba orukọ rere fun iṣẹ to ṣe pẹlu awọn ọdọ agbabọọlu ọdọ Chelsea. Eyi le jẹ ki wọn mu awọn mejeeji lati tukọ Stamford Bridge.

Bawo ni gbedeke ti wọn fi le rira agbabọọlu yoo ṣe pa akọnimọọg ba tuntun lara?

Bi Chelsea ko ba tilẹ le ra akọnimọọgba tuntun titi di 2020, o kere tan, agbabọọlu tuntun kan yoo wa nilẹ fun akọnimọọgba to ba wọle - Christian Pulisic, ti wọn ra pẹlu miliọnu lọna ọgọta o din meji Euro.

Ṣugbọn eyi to ja ju ni ki eniyan le ba awọn agbabọọlu ti oun funra rẹ ṣa ṣiṣẹ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Roman Abramovich ati Cesar Azpilicueta

Ki ni akọnimọọgba Chelsea ni lati ṣe ki wọn ma le?

Idahun ibeere yi ni wipe ko mu inu Abramovich dun. Ọrọ yi si lọju gan ni.

Sarri ni akọnimọọgba akọkọ ti yoo lọ ni ọna to wuu gan lati igba ti Abramovich ti ra Chelsea.

Awọn alatilẹyin Chelsea fẹran Jose Mourinho ati Antonio Conte, ṣugbọn ni ti Sarri, wọn ko fẹran rẹ. Wọn ni o n ṣe ifẹ inu rẹ ati pe ko mọ oun to n ṣe.

Idi rẹ to fi jẹ wipe nigba ti Juventus wa lati beere Sarri, inu Chelsea dun lati jọwọ rẹ.

Ṣe wọn o tun wa oludari bọọlu?

Will they look for a director of football?

Ọrọ kan to jade nigba ti Chelsea ba Arseal gba ninu Europa League ni wipe amule Chelsea nigba kan ri Petr Cech yoo pada wa gẹgẹ bii oludari pataki.

Ṣugbọn Cech ni ko si ootọ kan nibẹ nigba naa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Cech

Nitori naa, oun ti yiyan sipo eniyan kan bii Cech yoo ṣe ni lati mu aawọ to le wa laarin awọn to ni ẹgbẹ agbabọọlu ati akọnimọọgba kuro.

Ṣe akọnimọọgba yoo nipa lori bi awọn agbabọọlu yoio ṣe maa huwa?

Bo ti lẹ jẹ pe awọn akọnimọọgba Chelsea n yi pada, o ya ni lẹnu wipe ẹgbẹ agbabọọlu na ṣi n ṣe ribiribi.

Aawọ ti ṣẹlẹ tẹlẹ laarin awọn akọnimọọgba Chelsea ati awọn to di owó ẹgbẹ agbabọọlu mu, ko si da bi ẹni wipe eyi yoo yi pada.

Oun to ṣaa ṣe koko ni wipe, iru ẹni ti yoo gbe iṣẹ Sarri ru ni yoo tọka ibi ti Abramovich yoo ya si.