Nigeria Immigration Service: kò sí àjòjì darandaran kankan ní Nàìjíríà

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Kò sí àjòjì darandaran kankan ní Nàìjíríà ni ọrọ alukoro Nigeria Immigration Service

Àlejò tí kò bá ni ìwé ìgbélùú Naijiria n padà sílé ni -Babandede.

Adari ajọ to n ṣo ìgbòkègbòdò àwọn to n wọ orilẹ-ede Naijiria, Ọgagun Muhammad Babandede ni iroyin ni o ṣe ikede yii.

O ni ijọba ti fun gbogbo awọn alejo lati ilẹ okeere ni oṣu mẹta lati fi ṣeto iwe igbeluu wọn ni Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOdumakin sọrọ lori Fulani darandaran

Babandede sọ ọrọ yii lasiko ikẹkọọ-jade fun awọn ọmọ ogun mẹrindin ni irinwo lori ọrọ ẹṣọ aabo fun iwọle-ijade awọn eniyan ni Naijiria.

Eyi waye nile iṣẹ ikọni ti Nigeria Immigration Service (NIS) to wa ni Kano.

Babandede rọ awọn to kogoja to jẹ ẹleekẹrinlelogoji iru rẹ lati gbiyanju lori ipese aabo fun gbogbo olugbe Naijiria.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ilé iṣẹ́ aṣọ́bode orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti ni kò si àjòjì darandaran kankan lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà gẹ́gẹ́ àwọn ènìyàn ṣe ń sọ.

Nigba ti ile iṣẹ BBC kan si ilé iṣẹ́ tó n rísí ìwọlé-ìjáde ní Naijiria lori ọrọ yii ni Ogbeni Sunday James to jẹ alukoro NIS sọrọ ni kikun lori ọrọ naa.

O ni awọn ti Babandede n sọ ni awọn ti ko ni iwe aṣẹ lati gbe Naijiria ati pe Ọ̀FẸ́ ni wọn yoo ṣeto gbigba iwe igbeluu yii laarin oṣu mẹta to sọ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán O ni ijọba ti fun gbogbo awọn alejo lati ilẹ okeere ni oṣu mẹta lati fi ṣeto iwe igbeluu wọn ni Naijiria.

Sunday James ṣalaye pe igbesẹ yii waye lataari aṣẹ lati ọdọ Aarẹ Buhari pé ki wọn ṣeto iforukọ silẹ àwọn alejo to n wọ Naijiria.

O ni ọfẹ ni NIS maa ṣe e fun koda awọn ti wọn ti wọle lọna aitọ ti wọn ko ni iwe irinna atiwọle to jẹ ootọ.

Ṣe àwọn Darandaran ajoji lo n ṣọṣẹ́ ni Naijiria?

Ilé iṣẹ́ Nigeria Immigration Service ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti ni kò si àjòjì darandaran kankan lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bi àwọn ènìyàn ṣe ń sọ.

Ọgbẹ́ni Sunday James to jẹ agbẹnusọ fún NIS ló sàlàyé ọ̀rọ̀ náà lásìkò tó ń ba BBC sọ̀rọ̀ lónìí ọjọ́ Ajé.

O fèsì lori ìròyìn kan to jade tó sọ pé oṣù mẹ́ta ni gbèndéke ti àwọn fún àjoji ni orilẹ̀-èdè Nàìjíríà láti wá gba ìwé ìgbélùú tàbí ki wọn fi wọ́n ránṣẹ́ padà si orilẹ̀-èdè wọn.

Sunday James ni, àkọkọ sí ẹni ti ó wọ̀lú lọ́nà ti kò bá òfin mu, sùgbọ́n ọ̀nà àìṣe déédé nìkan ló wà.

O ni orilẹ-ede Naijiria ni ofin to de ki ẹnikẹni maa gbe ibọn kiri laiyọ awọn Fulani darandaran silẹ̀.

O mẹnuba agbara ti ileeṣẹ oun ni ati igbiyanju wọn lati daabo bo awọn ẹnubode Naijiria ati lati mojuto awọn to n wọle ti wọn n jade.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLadoja

Ni ipari, Sunday James rọ ẹnikẹni to ba kẹfin darnadaran kankan to wọ Naijiria lọn aitọ lati jẹ ki ileeṣẹ NIS gbọ sii.

O ni ki ẹni to ba ri alejo lati ilẹ okeere ti ko yẹ ko wa ni Naijiria tete fi to ileeṣẹ Immigration leti nitori aabo ati alaafia gbogbo olugbe Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÉégún tó wà nídí Yoruba Bollywood, Samo Baba f'ojú hàn o!

Sunday James ṣalaye fun BBC pe awọn darndarn to n wọ Naijiria jẹ eyi ti adehun ECOWAS faaye gba lati wọle.

O ni ko si akọsilẹ kankan nile iṣẹ wọn to ṣafihan awọn to ti wọ Naijiria lọna itọ tabi pẹlu ibọn lọwọ.