Kò dùn mí pé mo sọ̀rọ̀ tako Buhari -Adedayo Festus

Image copyright @SP
Àkọlé àwòrán Adedayo ni maa tun si maa so ooto oro lo ni

Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba ni Abuja ni oun ko le yan Festus mọ.

Adedayo Festus lo ṣe idanwo lati di oluranlọwọ pataki fun aarẹ Ahmed Lawan ki wọn to jaa ju silẹ.

Festus ṣalaye fun BBC pe ọrọ idaduro oun laarin wakata mejidinlaadọta lẹyin ti wọn yan oun ko dun oun ju.

BBC kan si Adedayọ lati gbọ iha ti ẹ latari ọrọ iyansipo rẹ to gba ori ayelujara kan.

Igba gbogbo ni Festus Adedayo maa n sọrọ lori ayelujara ni eyi ti awọn ololufẹ APC sọ pe o fi n ṣe lodi si ijọba Buhari ni.

Awọn eniyan APC ni ko ṣeeṣe fun ẹni to n sọ buruku nipa ẹgbẹ to n tukọ Naijiria lọwọ lati tun jẹ igbadun wọn.

Ọpọlọpọ ọrọ ni wọn ti sọ lori ayelujara tako Festus ki aarẹ ile igbimọ aṣofin to wa yọọ kuro.

Adedayọ ṣo fun BBC pe inu oun ko bajẹ si igbesẹ aarẹ ile igbimọ aṣofin rara.

O ni koda oun fi imoore han pe wọn ronu kan oun lati fi siru ipo ẹlẹgẹ bẹẹ.

Diẹ lara nkan ti awọn eniyan sọ:

Aisha Buhari gan an ti sọrọ lori koko yii pe:

O ni eyi ko sọ pe ki oun ri ootọ nilẹ ki oun ṣali sọọ ti ijọba Buhari ba n ṣe nkan ti ko yẹ.

O ni bi oun ko tilẹ ri ipo gba, ko le di oun lowo lati simi oro sisọ si ààrẹ Buhari, Tinubu ati awọn èèkan inu ẹgbẹ oselu to miran

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSogidi Lake: Kòṣẹja-kòṣèèyàn lá bá nínú adágún odò náà -Ojedele