Bá mi po ògì ní iṣẹ́ t'ọkọ mi rán mi gbẹ̀yìn -Funmi
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Widows Day 2019: Mo máa ń sá kiri wá owó ilé ni -Opó

Bá mi po ògì ní iṣẹ́ t'ọkọ mi rán mi gbẹ̀yìn -Funmi Babayẹmi

Opó ni obinrin tabi ọkunrin ti o padanu ọkọ tabi aya rẹ ni awujọ Yorùba.

Oriṣiiriṣii ero ni awọn eniyan maa n ni nipa opó paapaa opó obinrin ni awujọ wa.

Olufunmilọla Babayẹmi ni obinrin opó lati ọdun mẹrinla sẹyin ti o ṣalaye iriri rẹ lati tọ ọmọ rẹ mejeeji gẹgẹ bi opó.

O ni ọpọ igba ni awọn eniyan maa n ro pe opó fẹ gba ọkọ awọn ni eyi ti ko ri bẹẹ rara.

Arabinrin Funmilola sọrọ lori bi ọkọ rẹ ṣe ku, igbiyanju gbogbo ile lati doola ẹmi rẹ ati irinajo rẹ lati igba naa wa.

Funmilola ni ariwo Oluwa jọọ da mi si ki n le sin ọ dopin ni igbe ti ọkọ oun ké ko too ku.

O yi ero awọn eniyan pada pé opó kii ṣe arun, bẹẹ wọn kii ṣe gbọkọgbọkọ rara.

Imọran Funmilola fun gbogbo opo ni pe ki wọn sunmọ Olorun to jẹ ọkọ opo ati baba fun awọn alaini baba.

O ni atẹlẹwọ ẹni kii tan ẹni jẹ, ki onikaluku lọ gbajumọ iṣẹ rẹ.

Ati pe, o san ki ẹni ti ko le mu ara duro ko lọ fẹ ọkọ opo miran lai gba ọkọ ọlọkọ.