Jẹ́ kí a jọ sọ àǹfàní US fún Nàìjíríà -Osinbajo

osinbajo
Àkọlé àwòrán,

Ọrọ wa maa wọ̀ ti a ba jọ ran ara wa lọwọ

Igbakeji aarẹ Naijiria de si Amerika fún idagbasoke eto ọrọ aje Naijiria.

Ojọgbọn Yemi Osinbajo ṣe abẹwo si Amerika fun apero itẹsiwaju ajọṣepọ Naijiria ati Amẹrika.

Ile iṣe aarẹ ni Naijiria lo fi atẹjade kan sita tẹlẹ fi kede irinajo igbakeji aarẹ Naijiria lọ si New York.

Eto wa nibi ti Ojogbon Osinbajo a ti ṣe ipade pẹlu Mike Pence to jẹ igbakeji aarẹ ilẹ̀ Amerika ni Washington DC lọjọru.

Ogbeni Laolu Akande to jẹ olubadamọran igbakeji aarẹ ni abẹwo ọlọjọ mẹrin naa a bi eso rere si eto ọrọ aje Naijiria.

Igbakeji aarẹ ni aṣoju Naijiria si ilẹ Amerika, Adajọ-fẹyinti Sylvanus Nsofor ti gba ni kete to gunlẹ ni papakọ ofurufu J.F. Kennedy.

Bakan naa ni ọjọgbọn Osinbajo yoo sọrọ lori koko to jẹ mọ idagbasoke eto ọrọ aje Naijiria nibi apero kan ni Amerika.

Ireti wà pe igbakeji aarẹ yoo sọrọ lori ọna imubọsipo pada ati awọn anfani itẹsiwaju ti Naijiria ni nile ati loke okun.

Àkọlé fídíò,

Osinbajo: Ikẹnnẹ yẹ kó jẹ́ Mẹ́kà òṣèlú ni

Erongba abẹwo igbakeji aare si Amerika ni pe gba fun Raji nile to difa fun gba fun Gbada loko yoo ṣẹlẹ laarin Naijiria ati Amẹrika ti ohun gbogbo ba lọ bi o ti yẹ.

Ọjọgbọn Yemi Osinbajo yoo ṣe ipade pelu igbimọ ajọṣepọ ile okeere lasiko abẹwo yii.

Igbakeji aarẹ ni wọn gba pe yoo pada si Naijiria lọjọbọ to m bọ.

Àkọlé fídíò,

Widows Day 2019: Mo máa ń sá kiri wá owó ilé ni -Opó