Tomomewo Favour: olóṣèlú kìí ṣe ọ̀daràn tàbí alágbèrè

Ìbẹ̀rù, owó, ìpè pàjáwìrì fún mítìnì lóru kìí jẹ ki òṣèlú rọrùn fún obìnrin - Favour

Honorebu Tomomewo Favour to jẹ ọdọbinrin to n sọju ẹkun Ilajẹ Constituency sọ pataki ipa ọkunrin gẹgẹ bi oluranlọwọ fun obinrin to n ṣe iṣelu.

O sọ nipa iriri rẹ ni kikun ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Yoruba paapaa Ìdí tí obìnrin kò ṣe pọ̀ nínú òṣèlú Nàìjíríà .

Honorebu Favour ni iṣẹ ọwọ oun ni baba isalẹ oun ṣugbọn o sọ ipa pataki ti Arabinrin Betty Anyanwu Akeredolu ko ninu irinajo oṣelu oun.

Bẹẹ, ti a kò ba ri ẹni ba la ni ọrọ iṣelu ni Naijiria, ọ̀là kìí yá.

Bakan naa ni Favour sọrọ lori awọn ipenija ti oun koju lagbo iṣelu nitori aiko owo silẹ.

O ni ọpọlọpọ agba ẹgbẹ ni ko ṣe ti oun nitori oun kọ̀ lati maa pin owó.

Tomomewo gba awọn obinrin to ba fẹ wọnu iṣelu Naijiria lọ ni imọran.

O sọ bi wọn ṣe le koju ẹ̀rù obìnrin ninu iṣelu.