Air Canada: Obìnrin to jí nínú òkùnkùn nínú ọkọ̀ òfurufú

oko ofurufu
Àkọlé àwòrán,

Air Canada: Obìnrin to tají nínú òkùnkùn nínú ọkọ̀ òfurufú

Irinajo lati Quebec lọ si Toronto di a-lọ-di-oru -Tiffani Adams.

Airinjinna ni airi abuke ọkẹrẹ, Yoruba gbà pé ti eeyan ba rin jinna, o di dandan kó ri ekute onidodo.

Tiffani Adams ni obinrin kan to fidi ẹ mulẹ pe ko si ohun tuntun labẹ ọrun mọ ni papakọ ofurufu Toronto Pearson.

Kete to wọ inu ọkọ ofurufu Air Canada lati Quebec lo ba gbagbe sun lọ.

Ọrẹ Tiffani, Deanna Noel-Dale lo fi sita pe, ori ko ọrẹ oun yọ.

Iroyin naa ni ero ko pọ ninu baalu naa, fun idi eyi Tiffani nikan lo da joko si odindin ila kan ninu irirnajo ọhun.

O ni nigba ti Tiffani a fi ji saye, gbogbo ibẹ ti dudu.

Gbogbo ero ti sọ kalẹ, ko si eeyan kankan mọ ninu baalu.

Eyi to fihan pe ko ji titi baalu fi balẹ ti gbogbo ero si sọkalẹ tawọn oṣiṣẹ ọkọ ofurufu naa ti lọ.

Tiffani sọrọ lori iriri rẹ to ba ni lẹru pe niṣe ni aya oun ja bi oun ṣe ji ti gbogbo ẹ dudu.

O ni oun gbiyanju lati fi ina sori ẹrọ ibanisọrọ oun ṣugbọn ko ṣeeṣẹ.

Àkọlé fídíò,

Tomomewo Favour: olóṣèlú kìí ṣe ọ̀daràn tàbí alágbèrè

O ni nigba ti oun jaja ri atupa onibatiri kan ti o fi ṣe atẹrin de ibi to ti ri ilẹkun ọkọ ofurufu naa ṣi.

Lẹyin eyi lo rii pe ko si bi oun ṣe fẹ fo silẹ ni iwọn ẹsẹ bata aadọta.

Lo ba ri ọkunrin kan lara awọn to n ko ẹru ninu ọkọ ofurufu, to pee pe ko wa ran oun lọwọ.

Tiffani ni ẹ̀rù ba ọkunrin yii to di jinijini sii lara pé bawo leeyan a ṣe wa ninu ọkọ ofurufu di asiko naa.

O ni oun ba di ẹrujẹjẹ ninu papakọ ofurufu ọhun to di apewo.

O ni awọn alaṣẹ Air Canada ti bẹ oun lori ọrọ naa.

Àkọlé fídíò,

Widows Day 2019: Mo máa ń sá kiri wá owó ilé ni -Opó

Awọn alaṣẹ Air Canada ni awọn n ṣiṣẹ iwadii lori ọrọ naa lọwọ lai ṣe alaye ni kikun.

Bẹẹ, ẹni Ṣango toju ẹ wọlẹ, ko ni ba wọn bu ọba ko so ni, nitori pe Tiffani ni lati igba naa ni oun ko ti le sun dadaa nitori ẹ̀rù.