Orin kíkọ kò dí ìwé mi lọ́wọ́ rárá -Hameen School Boy
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Mo máa n forin mi kìlọ̀ ìwà ìbàjẹ́ láwùjọ ni -Hameen

Inu mi maa n dùn ti mo ba n kọrin -Hameen

Hassan Al-Hameen Williams ni ọdọmọde olorin ti BBC ba ni alejo lasiko yii.

O jẹ ọmọ ọdun mẹwaa to ti n kọrin lati ọdun marun un sẹyin.

School Boy to tun jẹ orukọ inagijẹ Hameen ni iṣẹ orin kikọ oun ko di iwe kika oun lọwọ nitori ọtọọtọ ni asiko wọn.

Hamen ṣalaye fun BBC pe orin kikọ dabi iwe, ẹbi ati aburo fun oun.

O ni igba gbogbo ni inu oun maa n dùn ti oun ba ti n kọrin.

School Boy ni ohunkohun ti eti oun ba gbọ, ati nkan ti awọn eeyan n ṣe ni agbegbe oun lo maa n fun oun ni imisi lati kọrin.

Ọdọmọde olorin yii ni oun maa n forin takasufe ti oun n kọ yii kilọ iwa ibajẹ ni awujọ wa.

School Boy ni oun fẹ dabi Davido ati Olamide ni.

Ati pe o wu oun ki oun maa kọrin yii kaakiri gbogbo agbaye ni.