Àwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá parapọ̀ láti gbógun ti ààbò tó mẹ́hẹ!

Ohun ti agba fi tẹlẹ ikun ni oro yii gba lasiko yii
Ọmọde gbọ́n, agba gbọ́n la fi da ilẹ̀ Ifẹ ni ọrọ eto aabo dukia awọn eniyan ipinlẹ Oyo, Ogun, Ondo, Oṣun, Ekiti ati Eko gba bayii.
Ọwọ́ ọmọde ko to pẹpẹ, ti agbalagba ko wọ keregbe ni apero yii gba nilu Ibadan loni.
Orọ awọn ọdaran Fulani darandaran, ọrọ awọn adigunjale, ọrọ awọn ajinigbe ni wọn jọ n wa ojutu sii.
Oluwo fẹ fi ọgbọn rẹ kun ohun to yẹ ni ilẹ̀ Yoruba
Ọba Oluwo, Oba Olugbo, Ọba Eleruwa, ati gbogbo alade lo n forikori pé kini ọna abayọ?.
Oro to ba gba ẹkun, a kii fi ẹrin sọọ
Arakunrin Fulani ni aigbede ara eni ni orisun ija pelu agbe
Oba kaakiri ilẹ̀ Yoruba lo peju pesẹ sibi apero ọna abayọ yii.
Gbongan Theophilus ni UCH kun fọfọ lataari ohun to n kọ awọn eeyan lominu
Awọn gomina ipinlẹ guusu iwọ oorun Naijiria ti ri ọrọ awọn ọdaran Fulani darandaran pe o gba ajọrọ gbogbo ile ni.
Mo ṣeleri lati fi ootọ inu sin awọn eniyan to dibo yan mi sipo.
Ohun to kọ iwaju si ẹnikan, ẹyin lo kọ si ẹlomii, bi ilu gangan ni ọrọ awọn Fulani darandaran ati ijinigbe yii n bi nibi apero to n lọ ọhun.
Ọrọ wa maa to ye ara wa nitori aabo awọn to yan wa sipo ṣe pataki
Awọn ladelade, loyeloye, ẹgbẹ awujọ ati awọn oniruuru ajọ eleto aabo lo ti pejo si Ibadan bayii.
Awọn gomina ẹkun iwọorun-guusu orilẹede yii korajọpọ lati ṣe ipade pajawiri lorii wahala awọn ajinigbe, iwa ọdaran ati eto aabo nilẹ Yoruba.
Gbogbo wọn lo ti peju po si gbagede ti ipade pajawiri lorii wahala awọn ajinigbe, iwa ọdaran ati eto aabo nilẹ Yoruba naa ti n waye.
'Fulani Ilorin l'ọkọ mi'
Ki lo bi apero yii lati ibẹrẹ?
Ọpọlọpọ iṣẹlẹ lo ti ṣẹlẹ lori eto aabo Naijiria lapapọ.
Bi awọn boko haram, ati aji ẹran ọsin gbe ati ikọlu awọn agbẹ ati darandaran Fulani ṣe n ṣelẹ ni oke ọya.
Bẹẹ naa ni ikọlu awọn agbesunmọmi, ajinigbe ati ija awọn ẹkun Naija-Delta n ṣẹlẹ.
Odumakin sọrọ lori Fulani darandaran
Ọ̀rọ̀ ètọ ààbò ilẹ̀ Yorùbá ti gba àpérò ọmọ eríwo, àwọn orí adé àti gómínà pé ìpàdé pàjáwìrì lórí ọ̀rọ̀ ìjínigbé.
O to gẹẹ lori ọrọ ikọlu nilẹ Yoruba
Gbogbo iṣoro ti ko fi àwọn eniyan Yoruba lọkan balẹ yii naa ni wọn ro papọ.
Ọrọ ti o kọju si ori ade de ibi pe, wọn fajuro to eyi
Oro to n gbomije loju arugbo ti di nkan mii fun ọdọ lawujọ.
Ibadan expressway: Àwọn olè Fulani ló ń jí ènìyàn, pànìyàn ní òpópópónà!
Igbagbọ wa ni pe ẹnu wọn a kò si ojutu iṣoro to n koju iran Yoruba ati Naijiria lapapọ yii.
Àwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá parapọ̀ láti gbógun ti ààbò tó mẹ́hẹ!
Ipade naa n lọ lọwọ ni gbọngan nla Theophilus Ogunlesi to n bẹ ladojukọ UCH nilẹ Ibadan.
Awọn gomina ti ireti wa wi pe wọn o darapọ mọ eto naa.
FFK: Buhari ló ń fún àwọn Fulani láàyè láti máa pa ènìyàn'
Bii Babajide Sanwo-Olu ti ipinlẹ Eko, Dapọ Abiọdun lati ipinlẹ Ogun, Rotimi Akeredolu ipinlẹ Ondo, Gboyega Oyetọla lati ipinlẹ Ọṣun, Kayode Fayẹmi ipinlẹ Ekiti ati gomina Ṣeyi Makinde ipinlẹ Ọyọ ti o jẹ olugbalejo.
Ọọni Ile-Ife, Ọba ẹnitan Ogunwusi, ati Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi naa n bẹ lara awọn alejo pataki ti wọn n reti nibi ipejọpọ naa.
Àwọn gómìnà Ìwọ̀-Òòrùn Nàìjíríà ṣe ìpàdé láti gbógun ti ààbò
Loni ni ipade ọhun n bẹrẹ.
Awon gomina mefa ni ekun iwo-oorun orile-ede Naijiria yoo ma a se ipade pelu oga ajo olopaa, ati awon eleto aabo lati wa ona abayo si isoro eto aabo to mehe ni agbeegbe naa.
Oríṣun àwòrán, Google
Ajọ to n risi igbelarugẹ ẹkun Iwọ-Oorun orilẹede Naijiria lo se agbatẹru ipade laaarin awọn gomina mẹfa lati gbogun ti eto aabo to mẹhẹ.
O ti se diẹ si isinyi ni awọn Fulani darandaran ti n se ọsẹ ni agbeegbe naa, ti o si fa ibẹru bojo fun awọn eniyan ni agbeegbe naa.
Ajọ to n risi igbelarugẹ ẹkun Iwọ-Oorun orilẹede Naijiria lo se agbatẹru ipade laaarin awọn gomina mẹfa lati gbogun ti eto aabo to mẹhẹ.
Mo máa n forin mi kìlọ̀ ìwà ìbàjẹ́ láwùjọ ni -Hameen
Yara igbalejọ Theophilus Ogunlesi Multipurpose Hall ni ipade naa yoo ti waye.
Akọroyin BBC News Yoruba ti wa nibẹ ni pese, lati ma a fi to yin leti bi o se n lọ.
Àṣà àti iṣẹṣe Yorùbá dì apewo ní Cotonou