Ope Bademosi: Ọmọọ̀dọ̀ tó pa Ope Bademosi ti rí ẹ̀wọ̀n gbére he!

Ope Bademosi Image copyright others
Àkọlé àwòrán Ọmọọ̀dọ̀ tó ń se oúnjẹ fún Olóyè Ope Bademosi nígbà ayé rẹ̀ ni ilé-ẹjọ́ ní ó jẹ̀bi ẹ̀sùn pípa ọ̀gá rẹ̀.

Ile-ẹjọ giga ni Igbosẹrẹ ni ipinlẹ Eko ti ran Sunday Anani to pa Oloye Ope Badamosi lọ si ẹwọn gbere.

Ọmọọdọ naa to wa lati orilẹ-ede Togo ni wọn fẹsun kan wi pe o hu iwa aitọ yii, ni ile Bademosi ni ile rẹ ni Parkview ni Ikoyi.

Adajọ Mobolanle Okikiolu-Ighile da ẹjọ naa lẹyin ti ọmọọdo naa jẹwọ wi pe lootọ ni oun fi ọbẹ kun ọga oun ni Ọjọ Kọkanlelọgbọn, Osu Kẹwa, ọdun 2018.

Ti a ko ba gbagbe, awọn ọlọpaa ri ọmọọdọ naa mu ni Osu kọkanla, ọdun to kọja ni ilu Ondo, lẹyin to fẹsẹ fẹ.

Arakunrin naa kọkọ sọ wi pe oun kọ lo pa ọga oun, wi pe awọn adigunjale lo se ikọlu si wọn.

Amọ, lẹyin igba to ri ara rẹ lori fonran to n sọ adugbo, lo wa jẹwọ wi pe lootọ ni oun gun ọga oun pa, lẹyin ti oun ji owo rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMo máa n forin mi kìlọ̀ ìwà ìbàjẹ́ láwùjọ ni -Hameen