'A máa ń fí oògùn olóró 'ginger'ká tó ka ẹsẹ bíbélì ni ṣọ́ọ̀ṣì'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

International Day Against Drug Abuse and Trafficking: ìdí ti mo fi ń mu oògùn olóró

Ko si ẹni ti kò le fi oogun oloro silẹ nitori o n ba ni laye jẹ ni - Seyi Adeyemi

Oni ni ni ayajọ gbigbogunti oogun oloro lilo ati gbigbe oogun oloro kiri ni agbaye fun ọdun 2019 ni eyi to jẹ ki BBC Yoruba wa awọn to ti lugbadi ẹ lọ.

Orisiiriṣii idi ni awọn eniyan ti wọn ti mu oogun oloro ri ti wọn ti pada fii silẹ ṣalaye fun BBC.

Seyi Adeyemi to muu ri fun ọdun mẹtalelogun kaakiri ipinlẹ Eko royin bi oun ṣe maa n dibọn tọrọ owo fi ra oogun oloro.

Dickson Agbaye sọ bi ọ̀rẹ́ ati akẹgbẹ ẹ ṣe sọọ di ọmọ ẹgbẹ okunkun to n fa oogun oloro pa.

Tosin Olaoluwa ni aini baba laye oun lo ṣakoba fun oun yatọ si nini ọrẹ tuntun ni adugbo tuntun.

Peter Awonuga so bi o ṣe n wa igboya lati ka bibeli ati bi awọn ọrẹ oun to jẹ ọmọ Pasitọ ṣe fa oun wọle atawọn nkan to sun oun de idi oogun oloro.

Ọmọọ̀dọ̀ tó pa Ope Bademosi ti rí ẹ̀wọ̀n gbére he!

Ọmọ onílẹ̀ wọ gàù, ó kó sí gbaga ọlọ́pàá

Ipò ètò ààbò ń já àwa gómìnà láyà, ó ń kọ wá lóminú - Àwọn gómìnà

Onikaluku ṣalaye bi wọn ṣe bọ nibẹ ati ọna abayọ.

Ọpọ iṣe wa lọwọ obi ati alagbatọ awọn eniyan to n mu oogun oloro.

Wọn gba pé Ijọba yẹ ki wọn ṣagbekalẹ ibudo idanipada-sipo lawujọ fawọn to n mu oogun oloro yatọ si fif ofin de e nikan.

'Oògùn olóró máa ń jẹ́ ki n bá ara mi jà, ti màá ṣerami léṣe'

NDLEA gbéṣèlé tọ́ọ̀nù mẹ́rìn oogun Tramadol

Opó ni mí, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ló ń rí opó bíi gbọkọgbọkọ

Bakan naa ni awọn ti wọn ti bọ lọwọ ajaga oogun oloro wọnyii parọwa fawọn ti wọn ṣi n muu pe, o ṣeeṣe lati fii silẹ.

Wọn gba pe ki awọn eniyan awujọ dẹkun ìdẹ́yẹsí awọn to n lo oogun oloro ti wọn ba n gbiyanju lati yi pada.