Kachikwu ó ṣeun, wá lọ simi- Ààrẹ Muhammadu Buhari

Thomas John Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Thomas John

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti yan Thomas John gẹ́gẹ́ bíí adele alága NNPC èyi to mú sáà Ibe Kachikwu wá sópin gẹ́gẹ́ bii mínísita epo rọ̀bì.

Adari apapọ NNPC tó ń k'ógbá wọlé lọ, Maikanti Baru, tó kéde ọ̀rọ̀ náà nílu Abuja sàlàyé pé alága tuntun yoo di ipo náà mú títí ti wọ́n yoo fi yan mínísíta abẹle tuntun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKayefi BBC Yorùba: Bàbá ọmọ, Mọ́ṣúárì, Ọlọ́pàá kẹ́jọ́ rò nípa òkú ọmọ tó pòórá

Baru fi kun pe alága tuntun yóò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ni wàrànsesà.

O fi kun pé Omowe John jẹ adari apaọ nígbà kan ri, ọmọ igbimọ adari ajọ NNPC

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionṢé ẹ̀yin lè ṣe jú àwọn tó f'àmì sí Awọlumatẹ?

Titi di igba ti Aarẹ yan John, Ibe kachikwu to jẹ minisita abẹle ni alaga igbimọ adari ajọ NNPC.

Thomas John yoo jẹ adele alaga gẹgẹ bi ilana abala ofin 11(3) ati 2(1) ti ajọ NNPC eyi to tumọ si pe yoo bẹrẹ iṣẹ loju ẹsẹ.

Gẹgẹ bi alakalẹ ofin naa, Aarẹ laṣẹ lati yan adele alaga.

Ohun díẹ̀ nípa Thomas John

  • Ọmọ ipinlẹ Cross River ni Thomas M.A John
  • Akẹkọgboye ninu im Chemical Engineering lati ile ẹkọ giga Prague Institute of Chemical Technology orilẹede Czech Republic ni.
  • O ti gboye Ph.D ninu imọ ẹkọ Reaction Kinetics ni Queen's University Canada.
  • John dara pọ mọ ajọ NNPC lọdun 1974 gẹgẹ bi amoju ẹrọ to si ti ṣamojuto ni ilu Warri ati Kaduna.
  • O goke agba di ga lẹnu iṣẹ yii titi ti wọn fi yan an gẹgẹ bii adari igbimọ adari ajọ NNPC.
  • O kọwe fipo silẹ funra rẹ lọdun 1992 lẹyin eyi to ṣe adari fun igbimọ ọpọlọpọ ile iṣẹ, lara wọn ni ile ifowopamọ UBA.
  • Oun ni oludasilẹ ati ọga agba ile iṣẹ amojuẹrọ Hydropec Engineering Company Ltd.