Ṣé ẹ̀yin lè ṣe jú àwọn tó f'àmì sí Awọlumatẹ?
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Tonal Marks: Ṣé ẹ̀yin lè ṣe jú àwọn tó f'àmì sí Awọlumatẹ?

BBC Yorùba ń gbìyànjú látí gbé àṣà Yorùbá díde padà.

Ede Yoruba dun lọrọ, paapaa julọ pẹlu ami ohun. Ede, aṣa, àti ìtàn orirun wà lára nkan to ya ogidi ọmọ Yorùbá sọtọ ni gbogbo agbaye.

Ede Yoruba dùn púpọ̀ ṣugbọn laisi àmì ohùn, o ṣeéṣe kó ma yé èèyàn dáadáa.

Ọrọ kan ṣoṣo maa n tumọ si nkan mẹrin nigba mii tabi ju bẹẹ lọ ni eyi ti ami ori wọn maa n fi iyatọ han bii ìgbà, igbà, ìgbá, àti igba.

O ya, ẹni ba laya ko wa wọọ.

Gbajugbaja ni ọrọ yii, Awọlumatẹ ninu awẹ owe Yoruba kan.

Ami ori ọrọ ṣe pataki ninu ede Yoruba, o si yẹ ka maa kọ ara wa, tabi ran ara wa leti.

Idi ree ti BBC Yoruba ṣe bọ sigboro, ta si ni ki awọn ọmọ Oodua fi ami si ori ọrọ Awọlumatẹ.