COZA: Fatoyinbo yẹ̀bá fún pẹpẹ ìwàásù fún ìwadìí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ tí wọ́n fi kàn án

Biodun fatoyinbo Image copyright Biodun fatoyinbo
Àkọlé àwòrán Ni ọjọ Ẹti iroyin jade nibi ti Busọla Dakolo ti fi ẹsun kan alufa Fatoyinbo ti ijọ COZA pe o fi ipa ba oun lo pọ

Mo yẹba fún pẹpẹ ìwáásù fún ìgbà dié- Pasitọ Biodun Fatoyinbo.

Lẹyin ọpọ awuyewuye to waye lori ẹsun ifipabanilopọ ti iyawo gbajugbaja olorin ni, Dakolo, iyẹn Busọla fi kan alufa agba ijọ Commonwealth of Zion Assembly, COZA, Biọdun Fatoyinbo, alufaa ijọ naa ni oun ti kọwe fi ipo silẹ fun saa diẹ.

Ninu atẹjade kan to fi sita loju opo Instagram rẹ lowurọ ọjọ Aje ni alufaa Fatoyinbo ti ṣe ikede naa.

O ni oun n yẹba kuro lori pẹpẹ iwaasu fun igba diẹ ni ibamu pẹlu imọran awọn agbaagba ijọ COZA ati ifẹ ti oun ni si iṣẹ Ọlọrun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Mo ti gba adura, mo si ti beere itọni lọwọ awọn aṣiwaju ninu irinajo igbagbọ kaakiri agbaye lori ọrọ to n ja ranyinranyin lori afẹfẹ.

Mo ti beere igbesẹ to yẹ ki n gbe, eyi ti yoo bu iyi fun Kristi ati iṣẹ to yan fun mi lati ṣe."

Alufaa Fatoyinbo ni oun mọ pe igbesẹ naa yoo tubọ mu ki oun le jọwọ ara oun silẹ fun awọn aṣiwaju oun lati tan ina wo hulẹhulẹ ọrọ naa.

Ni ọjọ Ẹti iroyin lu ori ayelujara pa nipa Busọla Dakolo to fi ẹsun kan alufaa Fatoyinbo pe o fi ipa ba oun lo pọ ni ọdun diẹ sẹyin.

Titi di bi a si ṣe n sọrọ yii, ọrọ naa ko tii tan nilẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWidows Day 2019: Mo máa ń sá kiri wá owó ilé ni -Opó