Elisha Abbo: Ilé ẹjọ́ sún ẹjọ́ Sẹ́nétọ̀ tó lu obìnrin síwájú

Elisha Abbo Image copyright Elisha Ishaku Abbo/Facebook
Àkọlé àwòrán Elisha Abbo

Ile ẹjọ kan ni ilu Abuja ti gba beeli Sẹnetọ Elisha Abbo pẹlu miliọnu marun-un Naira to fi mọ oniduro meji.

Adajọ ile ẹjọ naa, Abdullahi Ilellah sọ wi pe awọn oniduro rẹ mejeeji gbudọ ni adirẹsi ile ti wọn n gbe ni Abuja pẹlu aridaju.

Adajọ Ilellah wa sun ẹjọ naa siwaju di ọjọ ikejilelogun oṣu keje ọdun yii.

Gbogbo igbiyanju ati jẹ ki ekuru ọrọ Sẹnetọ Elisha Abbo to lu obinrin abilekọ kan ni ile itaja eroja ibalopọ ni ilu Abuja tan lawo, pabo lo ja si tori ọrọ rẹ ti de ile ẹjọ bayii.

Gẹgẹ bi igbakeji Supretendenti to tun jẹ agbẹnusọ ọlọpaa, Anjuguri Manzah ṣe fi aridaju rẹ han fun akọroyin BBC to ba a ni gbolohun lori ẹrọ ibanisọrọ, wọn ti gbe e lọ si ile ẹjọ.

Ṣugbọn Anjuguri ko fẹ ṣafihan orukọ ile ẹjọ ti wọn gbe e lọ. Ṣaaju eyi naa ni ọpọlọpọ eekan oloṣelu ti kọwe si ile iṣẹ ọlọpaa ti awọn naa ko si jafinra lori iwadii ọrọ naa.

Ọjọ Iṣẹgun ọjọ ikeji oṣu keje ni fidio iṣẹlẹ kan to ti ṣẹlẹ ṣaaju ọjọ naa jade to ṣafihan bi Sẹnetọ naa ṣe n lu obinrin kan nile itaja eroja ibalopọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFulani Kidnapping: Owó púpọ̀ la san kí wọ́n tó fi mi sílẹ̀

Bo tilẹ jẹ wi pe Elisha ti tọrọ aforijin pe "Ẹ má bínú, mo kábàmọ́ pé mo na obìnrin -Elisha Abbo" lọwọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria, awọn abiyamọ, ati obinrin to na pe ki wọn fi ori ji oun, oun ko ni hu iru iwa aidaa bayii mọ, o f da bi ẹni pe eyi ko ta leti awọn ọmọ Naijiria.

Abbo, to ni ọmọ kii mọ ẹkọ jẹ ko ma ra lọwọ, tun tọrọ aforijin lọwọ ijọ Ọlọrun lagbaye lori iwa aidaa ti oun hu yii, nitori o ni gẹgẹ bii asoju Kristi, iru iwa yii ko tọ si oun.

Awọn eniyan ni awọn gba pe o tọrọ aforiji o ṣugbọn bi ofin ba ti tọwọ bọ ọrọ, ko si pẹlẹ ma binu labẹ ofin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCAN: Samson ni ọrọ awọn ajinigbe ti gba àpérò ní Naijiria