Kò sí àrà tí a kò lè fi àgbón dá -  Gbenga Badagry
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Badagry ní ogún àjogúnbá tó pọ̀ yàtọ̀ sí òwò ẹrú

Mo n fi àgbọn kọ́ odindi abúlé - Gbenga Olusegun

Ilu Badagry jẹ ilu ti itan fihan pé owo ẹru gbilẹ nibẹ lasiko ijọba awọn amunisin laye atijọ.

Agbọn jẹ ọkan pataki lara ohun ti Eledaa jogun fawon ọmọ Badagry ni ipinlẹ Eko ni guusu Naijiria.

Ogbeni Gbenga Oluṣẹgun jẹ ọmọ Badagry to n fi agbọn ṣe iṣẹ ọ̀nà to wuu gẹgẹ bii iṣẹ oojọ rẹ.

Gbenga ṣalaye bi oun ṣe wa si Badagry fun isinmi lẹnu iṣe pẹlu iyawo oun ko to di pe oun wa di ẹni to n gbe agbegbe yii ni alaafia bayii.

O ni ohun gbogbo ni oun n fi agbọn Badagry da ni ara bii kikọ ilé, ilẹkẹ, ṣiṣẹ ohun ọ̀ṣọ́ ara ati tinu ile, ṣiṣẹ apamọwọ loriṣiirisi ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Gbenga gba pe awọn nkan wọnyii jẹ ohun iranti fawọn arinrin ajo afẹ ti wọn wa si Badagry.