Elisha Abbo: kí ẹnikẹni ma halẹ̀ mọ Kayọde mi, ẹjọ wà nile ẹjọ́

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán E ma halẹ Kayọde mi o -Abbo

Ohun to ṣẹlẹ nigba ti awọn aṣoju senetọ ti wọn yan fun iwadii nkan ti aṣojuṣofin Elisha Abbo ṣe pade ti n ja lori ayelujara bayii.

Lẹyin ti iṣẹlẹ ti Senetọ Abbo ti gba obinrin kan to n tọmọ leti nile itaja nkan ibalopo ni Abuja ni ọrọ yii ti di kari ayeẸ má bínú, mo kábàmọ́ pé mo na obìnrin -Elisha Abbo.

Lẹyin naa ni ọpọ awọn ọmọ Naijiria ti dide lodi si nkan ti ọdọmọde senetọ yii ṣe.

Oun naa si ti bọ si gbangba wa bẹbẹ pe Elisha Abbo ṣàlàyé ìdí tó fi lu obìnrin fún BBCiru rẹ ko ni ṣorọ lọwọ oun lẹyin ti awọn bii Atiku ti baa wi ninu ẹgbe PDP to ti n ṣoju ipinlẹ Adamawa.

Bayii, ti ẹjọ naa ti wa nile ẹjọ ti wọn si ti gba oniduro Senetọ Elisha ti ọrọ kan ni aarẹ ile igbimọ asọfin yan igibmọ kan lati ṣe iwadii ọrọ naa.

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Elisha Abbo: kí ẹnikẹni ma halẹ̀ mọ Kayọde mi, ẹjọ wà nile ẹjọ́

Bi Senetọ Olurẹmi Tinubu to n ṣoju ẹkun kan nipinlẹ Eko ati Seneto Abbo ṣe tahùn sira wọn lasiko iwadii ọhun lo tun ti di apero fawọn ọmọ Naijiria.

Bi awọn kan ṣe n yin Remi Tinubu pe ootọ ọrọ lo n sọ ni awọn mii ni ọrọ ko tọ sẹnu ọmọ iya ole ni o:

Bẹẹ naa ni awọn miran gba ọdọmọde Senetọ ti ẹnu n kun naa niyanju lati moju to ibinu ko too ma a gba ẹbọ lọwọ rẹ lawujọ.

Wọn ni kii ṣe ikoko, ati pe ko yẹ ki awọn akẹgbẹ rẹ laaye lati maa sọrọ buruku sii.

Awọn kan gba pé koko ipade naa ni ibaniwi fun Senetọ naa ati pe ohun ti o ṣe jẹ iwa idojuti fun gbogbo senetọ pata.

Loju awọn ọmọ Naijiria bii Ime- Albert, wọn senetọ yii kan bẹbẹ lori ahọn ni ati pe o yẹ ko gba ẹbi rẹ ni ẹbi ni o.

Awọn miran n fi oju sunnukun wo ọrọ Remi Tinubu pe, ṣe o ṣeeṣe fun awọn aṣojuṣofin lati daabo bo ara wọn gẹgẹ bii ibeere Remi Tinubu

Ni ipari awọn kan gba pe onile ni lọwọ, alejo naa di mẹru ni ọrọ awọn mejeeji