AFCON2019: Idije òní á yàtọ̀ láàrin Super Eagles ati BafanaBafana

A n gbe ife ẹyẹ AFCON bọ wa sile ni.

Lala maa lu ni alẹ oni nigba ti Bafana Bafana ẹgbẹ agbabọọlu South Africa maa gbena woju Super Eagles ti Naijiria.

Idije AFCON ti ilẹ Adulawọ ṣi n lọ lọwọ ni orilẹ-ede Egypt to n gbalejo ẹ.

Ọpọ ninu awọn ọmọ Naijiria gba pe ori Aare Buhari maa n gba ife ẹyẹ pe ati pé pẹlu adura, o maa ja si ọpẹ.