Bí Sanwo-Olu bá fún Super Eagles lówó ń kọ̀; Ṣebí kìí ṣ'owó ìjọba

Image copyright @:Sanwo-olu
Àkọlé àwòrán To ba wú Sanwo Olu o lè fún Super Eagles lowo to ju eyi lọ

Iye tó ba wu Sanwo Olu ló lè fún ẹnikẹni - Akoṣile

Laipẹ yii ni awọn iwe iroyin kan gbe e pe Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu fun awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ni miliọnu mọkanlelogoji o le diẹ lasiko to lọ fun idije AFCON 2019 to n lọ lọwọ ni Egypt.

Ọpọ lo ṣapejuwe igbesẹ naa gẹgẹ bi eyi ti ko ba oju mu, eyi to da bi iwa àpà.

Awọn kan ni ẹgbẹ oṣelu PDP tilẹ̀ ni Sanwo-Olu n fi owo awọn araalu ṣofo ni pẹlu igbesẹ naa.

Eyi mu ki BBC Yoruba o kàn si igbakeji akọwe iroyin fun gomina, Ọgbẹni Gboyega Akosile.

Akoṣile sọ fun akọroyin BBC to ba a sọrọ lọjọ kẹjọ, oṣu Keje, pe irọ patapata ni iroyin naa.

O ni gomina ko fun awọn agbabọọlu Super Eagles ni owo kankan.

Amọ ṣa, lọjọ kẹsan an, to jẹ ọjọ̀ keji, ni akọwe ipolongo fun ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, to jẹ ẹgbẹ gomina, Joe Igbokwe fi ikede kan sita pe ko si n to buru ti gomina ba ṣe bẹẹ.

O ni ti gomina ba ṣe e, o ṣe e lati mu ori awọn agbabọọlu naa wu ni fun bi wọn ṣe na ẹgbẹ agbabọọlu Camreoon.

Ọrọ̀ ti Igbokwe sọ yii mu ki BBC Yoruba o tun pada kàn sí Gboyega Akosile to ti kọkọ sọ̀ pe Gomina Sanwo-Olu ko fun Super Eagles ni owo kankan.

Ninu ọrọ to sọ lasiko yii, Akosile sọ pe bi igba ti awọn to n bu gomina lori igbesẹ naa kan n fi oju keere gomina ni.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBí Sanwo-Olu bá fún Super Eagles lówó ńkọ̀? Ṣebí kìí ṣ'owó ìjọba

O ni ''eelo ni gbogbo owo naa (41.4m) ti gomina ko le fun Super Eagles lati apo ara a rẹ, lai mu owo ijọba?''

Akosile sọ pe bi gomina ba ti ẹ ṣe bẹẹ, o ṣe e gẹgẹ bi baba to fẹ ki ọmọ rẹ o ṣe daadaa ni.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAFCON2019: Idije òní á yàtọ̀ láàrin Super Eagles ati BafanaBafana

Ṣugbọn Akọṣile yi tẹnumọọ fun BBC pé oun duro lori ọrọ àkọ́sọ oun pé Sanwo Olu kò fún ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles lowo.

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí