Lekki free toll: Àwọn ará ìpínlẹ̀ Eko kan sárá sí Sanwoolu

Ibodè Lekki
Àkọlé àwòrán Ibodè Lekki

Lẹyin ti gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwoolu ti kede pe ọfẹ ni awọn awakọ yoo kọja lẹnu ibode Lekki si Ikoyi, bi inu awọn eeyan ṣe dun ko ṣee fẹnu sọ.

Igboke gbodo ọkọ lọna yii ti awọn eniyan n pe ni Link Bridge lọ bo ṣe yẹ lonii ti igbesẹ ti gomina Sanwoolu gbe silẹ naa bẹrẹ.

Irina ọfẹ oni wakati mẹta yii ti pari fun tonii ti wọn si ti bẹrẹ si ni gba owo pada ni apa afara Admiralty lagbegbe Ikoyi niluu Eko.

Ijọba ipinlẹ Eko pa aṣẹ irina ọfẹ fun wakati mẹta laarọ ati nirọlẹ lago mẹrin abọ si mẹjọ abọ eyi to jẹ asiko ti ero maa n wọ pọ ju lati le mu adinku ba sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ.

Akọroyin BBC to ba awọn to wa nibẹ ni gbolohun fabọ jẹ ni pe ni kete ti wọn dawọ gbigba owo duro, ọna ṣi, igboke gbodo si n lọ bo ṣe yẹ ni wọọrọwọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOjo arọrọda Eko ṣe idiwọ fún káràkátà

Ṣugbọn ni kete ti wọn tun bẹrẹ si ni gba owo iwọle pada ni sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ tun gbera sọ.

Lara awọn awakọ to n gba ọna ibode naa kọja ni inu awọn ko dun ki awọn maa san owo ki awọn si tun maa jiya sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ.

Àkọlé àwòrán Ibodè Lekki

Ipinlẹ Eko ni ibudo kata kara to fẹ ju lorilẹede Naijiria bẹẹ naa si ni bii baraku ni sunkẹrẹ fakrẹ ọkọ jẹ ni ilu naa to bẹẹ to fi n ṣakoba fun ati oṣiṣẹ ọba to fi mọ awọn oniṣẹ aladani lojoojumọ.

Ẹwẹ gomina Eko kede irina ọfẹ yii lọjọru ọsẹ nigba to ṣebẹwo sibẹ lẹyin ipade pẹlu awọn tọrọ kan lori agbende agbegbe Lekki-Oniru ati awọn agbegbe Victoria Island.

Ipade naa wa gẹgẹ bi ọna abayọ si idamu sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ ati iṣẹlẹ omiyale ni agbegbe Lekki mọ Ajah.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionNISE NI OJO TO RO LEKO KUN OJU TITI