Afenifere: Ọ̀rọ̀ tó ń jáde lójú òpó ayélujára

Funke Ọlakunrin Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Funke Ọlakunrin

Pẹlu iroyin ojiji ti ọpọlọpọ n sọ nipa iku ọmọ alaga ẹgbẹ Afenifere ti ilẹ Yoruba, ọpọ gbọ yii sọ yii lo ti n jẹ jade lori boya Fulani daran daran tabi awọn agbebọn lo pa Funkẹ Ọlakunrin.

Lasiko to n fi idi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba, agbẹnusọ fun ẹgbẹ Afẹnifẹre, Yinka Odumakin salaye pe lootọ ni isẹlẹ naa waye, asiko ti Ọlakunrin n bọ lati ilu Akurẹ si lo se alabapade iku ojiji naa.

Baba oloogbe naa ni alaga ẹgbẹ Afẹnifẹre, alagba Reuben Fasoranti.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀgbà ni Obasanjo, oun tó ń sọ yé e, ìjọba ni kó tají - Wale oke

Lasiko to n fi idi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba, agbẹnusọ fun ẹgbẹ Afẹnifẹre, Yinka Odumakin salaye pe lootọ ni isẹlẹ naa waye, asiko ti Ọlakunrin n bọ lati ilu Akurẹ si lo se alabapade iku ojiji naa.

Ẹwẹ latari ati fi ọrọ ikini ku ara fẹraku ranṣẹ si alagba Fasoranti, oriṣiriṣi ẹda ọ̀rọ̀ lo n jẹyọ latẹnu awọn eekan Naijiria to ti fi ọrọ ranṣẹ si baba oloogbe naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCAN: Samson ni ọrọ awọn ajinigbe ti gba àpérò ní Naijiria

Aarẹ Buhari Buhari ti gba ẹnu ẹgbẹ oṣelu APC ki alagba Fasoranti pe oun ba a kẹdun ipapoda ọmọ rẹ ti awọn ti Ọlọpaa ipinlẹ ṣapejuwe gẹgẹ bii janduku apaayan pa lọna Ondo si Ọrẹ. Aarẹ si fi adura le ibanikdun rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFulani Kidnapping: Owó púpọ̀ la san kí wọ́n tó fi mi sílẹ̀

Ni ti Atiku Abubakar, o bu ẹnu atẹ lu ipaniyan to ba ni lọkan jẹ pupọ yii o si pe awọn oṣiṣẹ alaabo lati bẹrẹ iwadii gidi lati mu awọn to ṣekupa arabinrin naa. Loun naa ba fi adura ranṣ si Oloye Reuben Fasoranti ati ẹbi ati gbogobo ẹgbẹ Afenifere.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFFK: Buhari ló ń fún àwọn Fulani láàyè láti máa pa ènìyàn'

Ẹwẹ, Femi Fani Kayode ni oun ti ba arakunrin oun, Yinka Odumakin to jẹ agbẹnusọ fun ẹgbẹ Afenifere to si sọ fun oun pe awọn Fulani daran daran lo pa Ọmọ Baba Fasoranti. Fani Kayode wa fi eyi kan si iran Yoruba lati gbe igbesẹ ni waransesa lati da abo bo awọn eeyan wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Fulani Ilorin l'ọkọ mi'