Professor Wole Soyinka láti kékeré

Wole Soyinka Image copyright Getty Images, @IfeePeter

Iku Olokun Ẹṣin (Death and the King's Horseman)

Kongi's Harvest: A Play (Three Crowns)

Myth, Literature and the African World

Ake : The Years of Childhood

The Lion and the Jewel

Mandela's Earth: And Other Poems

Ibadan: A Memoir 1945-1967

Isara: A Voyage around "Essay"

A Dance of The forest

Opera Wonyosi

Early Poems

African Theatre

Jero Plays

... àtí ọpọlọpọ ti ẹ ba ranti ti ko lonka

Diẹ lara awọn awọn iṣẹ ọwọ Ọjọgbọn Wole Soyinka ree loke.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIfọrọwanilẹnuwo pẹlu Ọjogbọn Wọle Soyinka

Igi araba ni Akinwande Oluwole Babatunde Soyinka nile ati lẹyin odi gẹgẹ bi ọmọ kaaro o jiire ati ọmọ Naijiria ṣugbọn Wole Soyinka sọọ ni awọn eeyan mọ ọ si.

Ọmọ bibi ilu Isara-Remo ni Ọjọgbọn Wole Soyinka jẹ to si jẹ ẹlẹkeji ninu ọmọ mẹfa ti iya rẹ bi ni ilu Abeokuta ipinlẹ Ogun. Wọn bi i lọjọ kẹtala, oṣu keje, ọdun 1934.

Baba Wole, Samuel Ayodele Soyinka jẹ olufọkansin alufa ijọ Anglican ati adari ile iwe alakọbẹrẹ ti iya rẹ, Grace Eniola Soyinka si jẹ ontaja o tun jẹ ajafẹtọ nipa oṣelu laarin awọn obinrin.

Nitori naa, ọgba inu ile ijọsin Anglican ni wole Soyinka gbe ni kekere to si n kọ ẹkọ nipa ẹsin Kristẹni lọdọ awọn obi rẹ.

Amọ, bo ṣe n kọ eyi naa lo tun n kọ imọ nipa aṣa ati ẹsin Yoruba lọdọ baba baba rẹ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Wole Soyinka

Wọn kọ ọ dagba nile igbagbọ to si n kọrin laarin awọn ẹgbẹ akọrin ṣugbọn nigba to ya, Soyinka pada di alailẹsin kankan ti ko gbagbọ ninu Ọlọrun.

Onkọwe ere, onkọwe arosọ ati arokọ, iwe kika fun akẹkọọ to gbaju gbaja kọja afẹnusọ ni Wole Soyinka pẹlu ọpọlọpọ ami ẹyẹ ati ami idanimọ to ti gba ko lonka. O tun jẹ ajijagbara fun oṣelu.

Bakan naa, Wole Soyinka tun ni awọn aṣayan ọrọ bi owe to fi mọ akanlo ede to ṣe pe ọlọgbọn lo lee tu u.

Wole Soyinka ni ọmọ ilẹ Afirika akọkọ to kọkọ gba ami ẹyẹ Nobel Prize ninu imọ Litiresọ lọdun 1986.

O ka iwe nilẹ yii bii ile iwe alakọbẹrẹ niluu Abeokuta ati Girama ni Abeokuta ko to lọ si Government College, Ibadan ko to mori le oke okun fun ile iwe giga fasiti University College and University of Leeds, England.

Loke okun, o mu ajo iṣẹ pọn pẹlu Royal Court Theatre, London nibi ti o ti kọ ọpọlọpọ iwe to si ṣe agbejade rẹ ni Naijiria ati loke okun.

Image copyright Getty Images

Ninu itan oṣelu Naijiria, o kopa ipa ribiribi paapaa ninu jija fitafita fun gbigba ominira lọwọ awọn oyinbo amunisin.

Fun apẹrẹ lọdun 1965 o wọ ile igbohunsafẹfẹ Western Nigeria Broadcasting Service nigba naa o si kede ipe fun ki wọn fagile idibo ẹkun Ila Oorun Naijiria.

Bakan naa lọdun 1967 ijọba Ọgagun Yakubu Gowon mu u si atimọle ọdun meji.

Oniruuru ọna ni Soyinka maa n gba bu nu atẹ lu iṣejọba Naijiria paapaa awọn to n ṣe ijọba apaṣẹ waa atawọn oloṣelu jagidijagan mii, ọna ọlọgbọn si lo maa n lo eyi to tun lee jẹyọ ninu awọn iwe rẹ nigba mii.

Koda awọn ohun to kọ nigba mii a maa ta ba orilẹede mii tayọ Naijiria.

Lasiko ijọba Ọgagun Sanni Abacha laarin ọdun 1993 si 1998, Soyinka fi Okada Alupupu fẹsẹ fẹẹ kuro lorilẹ-ede Naijiria, o gba ọna "NADECO" iyẹn ibode Benin jade.

Laisi nile rẹ, Abacha kede pe pipa ni wọn yoo pa a.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOlusegun Obasanjo: Ọmú ìyá mi ti mo fi ń mùkọ ni kekere ló jẹ ki ń lókun

Ṣugbọn nigba ti ijọba alagbada yoo fi pada si Naijiria lẹyin iku Sanni Abacha lọdun 1999, Soyinka pada wa sile.

Lọdun yii kan naa ni wọn gbe e ga gẹgẹ bi Ọjọgbọn agba (Professor Emeritus) nile iwe giga fasiti Obafemi Awolowo University to ti jẹ olukọni ninu imọ Litiresọ.

Kii ṣe orilẹ-ede Naijiria nikan lo ti ṣe olukọni fasiti, o kọ ni ni fasiti Cornell University, United States ninu imọ nipa ilẹ Afirika ati imọ Tiata, bakan naa ni Emery university nibi to tun ti gba oye Ọjọgbọn Robert W. Woodruff Professor of Arts.

O tun ti kọni ni fasiti Oxford, Havard ati Yale ati bẹẹ bẹẹ lọ loke okun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Igbeyawo ati Idile Wole Soyinka

Iyawo aarọ Wole Soyinka, Barbara Dixon ti wọn si ni ọmọ̀kunrin kan, Olaokun Soyinka.

Lẹyin iku Barbara, Wole fẹ ara orilẹ-ede Naijiria mọ Liberia, Olaide Idowu lọdun 1963. Iyawo to fẹ gbẹyin ni Folake Doherty lọdun 1989.

Gbogbo ọmọ Wole Soyinka jẹ marun un, obinrin mẹta (Peyibomi Soyinka Airewele, Moremi Soyinka Onijala, Iyatade Apampa) ati ọkunrin meji (Olaokun Soyinka, Makin Soyinka).

Ninu oṣu kejila, ọdun 1962, Soyinka da ẹgbẹ awọn onimọ Tiata orilẹ-ede Naijiria silẹ.

Nigba to di ọdun 1964, o kọwe fipo rẹ silẹ ni fasiti gẹgẹ bi ifẹhonu han lori agbara aitọ ti awọn alaṣẹ ile iwe n lo lori wọn eyi to jẹmọ gbigbe lẹyin ijọba to wa lode.

Lẹyin eyi, Wole Soyinka tun ti di ọpọlọpọ ipo nla mu ni ẹka imọ ede Gẹẹsi ni fasiti ti ilu Eko.

Lẹyin ti iṣejọba Naijiria yi pada lọdun 1975 Soyinka pada wale lati tẹsiwaju iṣẹ rẹ ni fasiti Ile Ifẹ.

Soyinka tun da awọn ẹgbẹ mii silẹ to ni ṣe pẹlu ere Tiata, Aṣa ati iṣe Yoruba.

Yatọ fun itan to wa ni akọsilẹ nipa Ọjọgbọn yii, manigbagbe ni awọn iriri ti awọn aladani ti ni pẹlu rẹ ti wọn ṣi tun n ni tori aaye ọtọ ni Wole Soyinka wa.

Titi di akoko ti a ko iroyin yii jọ tii ṣe ọjọ ikẹtala, oṣu ikeje, ọdun 2019, Wole Soyinka ti pe ẹni ọdun marunlelọgọrin (85) ti gbogbo agbaye si n ṣe ayẹsi rẹ.