Nigeria Kidnapping: Ọ̀gá ọlọ́pàá Adamu Pàṣẹ́ iṣẹ́ àkànṣe nílẹ̀ Yorùbá

Image copyright @NPF
Àkọlé àwòrán Ọ̀gá ọlọ́pàá Adamu Pàṣẹ́ iṣẹ́ àkànṣe nílẹ̀ Yorùbá

E lọ gbọn gbogbo opopona marọsẹ guusu Naijiria yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́ - Oga ọlopaa Adamu

Adari agba fun gbogbo agbofinro Naijiria, Mohammed Adamu, ti kede pe ki awọn ọlọpaa kogberegbe fọnka si ẹkun Guusu Naijiria.

Adamu ni ki wọn lọ yẹ gbogbo opopona marosẹ to wa ni ẹkun Guusu-guusu ati Guusu ila oorun ati iwọ oorun Naijiria wo.

"Operation Puff Adder" ni o pe iṣẹ akanṣẹ ọhun.

Iṣẹ akanṣe "Operation Puff Adder" yii naa ni wọn ṣe agbekalẹ rẹ lati gbogun ti iṣoro eto aabo to wa ni opopona Kaduna si Abuja.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCAN: Samson ni ọrọ awọn ajinigbe ti gba àpérò ní Naijiria

Ohun ni wọn fi n gbogun ti iṣoro awọn darandaran ati gbewiri to n ṣọṣẹ nibẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa bẹrẹ igbesẹ tuntun yii lẹyin ti awọn ti ọlọpaa pe ni agbebọn pa ọmọ olori Afẹnifẹre, Funke Olakunrin ni opopona Kajola si Orẹ.

Oga agba Adamu ni igbese yii di dandan lasiko yii kiru rẹ ma ba a tun ṣẹlẹ mọ ni Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionArakunrin Fulani ni aigbede ara eni ni orisun ija pelu agbe

Bakan naa ni Adamu ni inu oun ko dun si ki arugbo maa fomije ṣọfọ ọmọ wọn lagbalgba.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Fulani Ilorin l'ọkọ mi'

Oga àgbà àwọn agbófinró ní Naijiria, Mohammed Adamu ti pàṣẹ iṣẹ́ àkànṣe "Operation Puff Adder" ní Guusu Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOdumakin sọrọ lori Fulani darandaran

Adamu fi da Oloye Reuben Fasoranti loju pe oun a rii pe agbara ofin mu awọn oniṣẹ ibi ti awọn ọlọpaa pe ni agbebọn.

Frank Mba to jẹ agbẹnusọ fawọn agbofinro lo fi lede pe awọn akọṣẹmọṣẹ ni ileeṣẹ ọlọpaa ti da si ilẹ iran Yoruba lati mu awọn ika eniyan yii.

Ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria lo ti n sọ fun awọn agbofinro lati ṣe ohun to yẹ ki wọn gbajumọ eto aabo Naijiria.

Koda ajọ SERAP gan an ti fi sita pe eto aabo ti n gbẹbọ ni Naijiria bayii:

Iku ọmọ olori afẹnifẹre yii lo ti n bi ige tai adubi pẹlu ọpọlọpọ ibeere lori iṣejọba aarẹ Buhari lasiko yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFulani Kidnapping: Owó púpọ̀ la san kí wọ́n tó fi mi sílẹ̀