Olórí Ọ̀dọ́ l'Ondo ní oníkálùkù yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní jà fúnra wọn
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Fasoranti: Àwọn ọ̀dọ́ Ondo fárígá lórí ikú Funke Olakunrin

Àwọn ọ̀dọ́ ipinlẹ Ondo tu sita lati fẹhonu han lori ọpọ ọsẹ ti awọn to n pa eeyan ni ipinlẹ wọn paapaa nigba ti awọn ba n rinrinajo.

Lẹyin ti awọn agbebọn pa Funke Olakunrin to jẹ ọmọ adari ẹgbẹ Afẹnifẹrẹ lorilẹ-ede Naijiria, iṣẹlẹ naa wu ọpọlọnu irunu jade lọdọ awọn ọmọ Naijiria.

Lara eyi naa lo mu ki awọn ọdọ ipinlẹ Ondo figbe ta pe o ti to gẹ pe ki awon Fulani kuro lagbegbe awọn, tori awọn kan n sọ wi pe awọn lo wa nidi iku rẹ.

Adekanbi Oluwatuyi to jẹ olori ọdọ ni gbogbo ilu Akure sọ fun BBC Yoruba pe gbogbo agbaye mọ pe iṣẹ agbẹ lo wọpọ ju lagbegbe awọn ṣugbọn gbogbo eniyan lo ti sa kuro l'oko.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ṣe ni wọn n tẹnu mọ ọ pe awọn Fulani darandaran ti gba gbogbo ilu awọn tan wọn si ti n ke si ijọba titi titi ti ko si oun ti ijọba ṣe.

Olori ọdọ ni ohun to ku tawọn yoo ṣe ni ki onikaluku maa ja funra wọn.