Siasia: Ọlọ́pàá Bayelsa ṣalàye ibi tí wọ́n bá ìyá Siasia tó bọ́ sọ́wọ́ ajínigbé

Samson Siasia Image copyright Other

Iroyin to tẹwa lọwọ latọdọ ile iṣẹ Ọlọpaa Bayelsa ni peawọn agbebọn ya wọ ile arabinrin Beauty Siasia wọn si ji i gbe lọ.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Bayelsa, SP ASinim Butswat fi ranṣẹ si ile iṣẹ BBC o fi aridaju han pe lootọ ni wọn ji iya agbabọọlu ati akọnimọọgba Naijiria tẹlẹ ri, Samson Siasia gbe.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOlórí Ọ̀dọ́ l'Ondo ní oníkálùkù yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní jà fúnra wọn

Atẹjade naa ṣalaye pe ni nkan bi agogo meji oru ganjọ ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu keje ọdun 2019 ni awọn agbegbọn ti ẹnikẹni ko mọ gba ọna oju omi River Nun wọ ile Arabinrin Beauty.

Ẹni ọdun ọgọrin ọdun ni Arabinrin Beauty to n gbe ni ilu Odoni ni ijọba ibilẹ Sagbama ipinlẹ Bayelsa ti wọn si ji i gbe lọ gba ori omi lọ si ibi ti ẹnikẹni kò mọ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Kọmiṣana ọlọpaa ipinlẹ Bayelsa ni atoun ati ikọ amuṣẹya awọn ti ṣe ibẹwo si ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye ati pe ile iṣẹ awọn pẹlu ajọṣep awọn mii tọrọ kan nipa aabo ti kan lu agbami wiwa awọn agbenipa yii ati lati doola iya ti wọn ji gbe.