BBC Yoruba: Àwọn ìròyìn tó tayọ lọ́sẹ̀ yìí

Akojọpọ Iroyin Image copyright BBC, OTHERS
Àkọlé àwòrán Akojọpọ Iroyin

Lati ọjọ́ aiku ti ọsẹ n bẹrẹ, oniruuru ni awọn iroyin to maa n jade lati akata BBC Yoruba. Bí wọn se pọ to, awọn koko iroyin kan wa to jẹ manigbagbe.

Yinka Ayefele di Bàbá ìbẹta

Image copyright @Yinkaayefele

Gbajugbaja olorin ni to tun jẹ oludaleeṣẹ rẹdio silẹ, Yinka Ayefẹlẹ ti di baba ibẹta bayii.

BBC Yoruba ba gbajugbaja olorin nni to tun jẹ oludaleeṣẹ redio silẹ, Yinka Ayefẹlẹ sọrọ lati fi aridaju rẹ han pe ni bayi, o ti di baba ibẹta lootọ.

Ṣaaju ni nkan bii oṣu diẹ sẹyin ni iroyin kan tan kalẹ pe o bimọ ti o si ni irọ ni awọn eniyan n pa.

Ṣugbọn ni bayii oun funra rẹ lo tu iroyin ayọ yii fun awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ redio rẹ pe.

Lati mu aridaju wa fun yin la fi ṣe ifọrọwanilẹnuwo yii pẹlu baba ibẹta gan funra rẹ to si ṣalaye gbogbo ọrọ.

Ẹkunrẹrẹ lori iroyin yii wa ni:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYinka Ayefele: Oṣù àwọn ìbẹ́ta mi kò pé ní kò jẹ́ kí n kọ́kọ́ kéde ìbí wọn

Ṣé kí àwọn Fulani Darandaran padà sílé tàbí dúró síbi tí wọ́n wà?

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Fulani Darandaran

Ìbẹ̀rẹ̀ ọrọ yii gan ni asiko ti ijọba apapọ ni awọn fẹ da eto RUGA Settlement silẹ eyi ti ọpọlọpọ ti fun ni itumọ tiwọn ti wọn si fẹ loju kaakiri gbogbo ipinlẹ orilẹede Naijiria.

Ileeṣẹ aarẹ orileede Naijiria ni ohun iyalẹnu lo jẹ fawọn bi awọn Gomina ipinlẹ kan ti ṣe n tapa si idasilẹ agọ Fulani, eyi ti wọn pe ni ''Ruga Settlement.''

Bẹẹ naa ni awọn Gomina ipinlẹ kan kilọ fun ijọba pe, ko ma ṣe daba lati da awọn agọ wọnyii silẹ lagbegbe awọn.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ aarẹ, Femi Adesina sọ fun BBC pe, awọn ni akọsilẹ ibi tawọn Gomina kan ti fọwọ si kikọ ọgba fun dida ẹran, lati fi dẹkun wahala to n waye laarin awọn agbẹ ati darandaran.

Ẹkunrẹrẹ lori iroyin yii wa ni:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCAN: Samson ni ọrọ awọn ajinigbe ti gba àpérò ní Naijiria

Alhaji Sikiru Ayinla Kollington: Rashidi Yekini ṣì ni mí b'óbìnrin bá sún mọ́ mi

Àkọlé àwòrán Alhaji Kolington

Gbajugbaja olorin Fuji nni, Alhaji Ayinla Kollington ti kede fun araye pe titi aye ni akọrin Waka nni, Alhaja Salawa Abẹni yoo maa jẹ iyawo oun, ti awọn yoo si jọ pẹ fun ara awọn.

Kollington kede eyi lasiko to n dahun ibeere lori eto BBC Yoruba, tun salaye pe obinrin to bi ọmọ fun ni, ti kuro ni ale ẹni, ọmọ mẹta si ni Salawa Abẹni bi fun oun, nitori naa, iyawo oun nii se.

Bakan naa o mẹnu ba a pe lootọ ni ija wa laarin oun ati Alhaji Ayinde Barryster sugbọn bii ti iku kọ tori "bi kii ba ṣe Barry ni iṣẹ aṣọle ni mi o ba maa ṣe".

Ọrọ pọ ninu iwe kọbọ ti gbajugbaja olorin yii tu sita fun BBC Yoruba.

Ẹkunrẹrẹ lori iroyin yii wa ni:

Ikọ̀ Super Eagles padà wálé lẹ́yìn tí wọ́n tún gba Bronze lẹ́ẹ̀kẹjọ

Àkọlé àwòrán Super Eagles

Diẹ to ninu nnkan oni nnkan, eyi lo difa fun ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria, Super Eagles ti wọn ipo kẹta tawọn nnkan n pe ni golden bronze ninu idije AFCON 2019.

Lẹyin iṣẹju mẹta pere ti wọn bẹrẹ ere bọọlu ọhun ni ẹlẹsẹ ayo, Odion Ighalo gba bọọlu sawọn eyi to fun Naijiria lanfani lati siwaju ninu ifẹsẹwọnsẹ to kangun si aṣekagba.

Bi a ba ka a ni meni meji, igba ikẹjọ ree ti ik Super Eagles yoo gba ami ẹyẹ baba kan naa, Bronze.

Ni bayii, ikọ naa ti pada wale pẹlu akọnimọọgba wọn, Gernort Rohr.

Ẹkunrẹrẹ lori iroyin yii wa ni:

Face App: Ẹ wo báwọn òṣèré tíátà kan yóò ṣe rí lọ́jọ́ ogbó

Image copyright LATEEF ADEDIMEJI
Àkọlé àwòrán Oṣere Nollywood

Pitimu ni awọn oju opo ayelujara Facebook, Instagram ati Twitter kun fun App ori ayelujara kan ti wọn n pe ni Face App lọsẹ yii.

Ọpọlọpọ awuyewuye lo ti n lọ lori lilo ẹrọ to n pa ọjọ ori ẹni da FaceApp, ti o le mu ki aworan eniyan kere sii ni ọjọ ori, abi ki o dabi arugbo.

Gbogbo oju opo ayelujara lo ti kun bayii fun fọto awọn oṣere tiata, ti wọn parada di arugbo bẹ si ni awọn ọmọ Naijiria naa ti dara pọ mọ eyi.

Ẹkunrẹrẹ lori iroyin yii wa ni:

Yánpọn yánrin lórí ikú ọmọ Alága ẹgbẹ́ Afenifere, Fasoranti

Image copyright OTHER
Àkọlé àwòrán Alagba Reuben Fa#soranti ati Oloogbe Funke Olakunrin

Pẹlu iroyin ojiji ti ọpọlọpọ n sọ nipa iku ọmọ alaga ẹgbẹ Afenifere ti ilẹ Yoruba, ọpọ gbọ yii sọ yii lo ti n jẹ jade lori boya Fulani daran daran tabi awọn agbebọn lo pa Funkẹ Ọlakunrin.

Lasiko to n fi idi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba, agbẹnusọ fun ẹgbẹ Afẹnifẹre, Yinka Odumakin salaye pe lootọ ni isẹlẹ naa waye, asiko ti Ọlakunrin n bọ lati ilu Akurẹ si lo se alabapade iku ojiji naa.

Baba oloogbe naa ni alaga ẹgbẹ Afẹnifẹre, alagba Reuben Fasoranti.

Ẹkunrẹrẹ lori iroyin yii wa ni:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFasoranti: Dẹ́rẹ́bà tó wa ọmọ Fasoranti ṣàlàyé bí wọ́n ṣe pa Funke Olakunrin

Awọn Iroyin ti ẹ le nifẹ si