RUGA: Gómìnà ìpínlẹ̀ Kano ní gbogbo Fulani lè máà bọ̀ lọ́dọ̀ àwọn

Fulani Darandaran Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Fulani Darandaran

Ọrọ lori boya ki awọn fulani Darandaran maa pada lọ ẹkun ariwa Naijiria gẹgẹ bi ẹgbẹ awọn agba ẹkun naa, NEF ṣe ke si wọn duro nibi ti wọn ba wa ti di ohun a n gba bi ẹni gba igba ọti.

Lana ode oni ni ẹgbẹ awọn gomina ni iwo-oorun Naijiria sọ pe awọn Fulani darandaran ni anfaani lati duro nile Yoruba. Leyii to jẹ wi pe awọn kan ti kọkọ ni afi laa igbesẹ RUGA ti ijọba gbe lati kọ Gaa fun wọn ko le fẹsẹ mulẹ lagbegbe awọn.

Ṣugbọn lẹyin ti awọn gomina kan ti ni ko saaye fun eyi ti awọn kan si nawọ soke paapaa ni iha ariwa pe awọn nifẹ si eto RUGA, Ẹ wo ìpínlẹ̀ 15 tó faramọ́ ìdásílẹ̀ àbúlé Ruga.

Oriṣiriṣi ọrọ lo tun ti n jade bii ka maa yi ẹnu pada.

Koda, gomina Abdullaji Ganduje ti ipinlẹ Kano ni gbogbo Fulani Darandaran nibikibi ti wọn ba wa ni Naijiria le maa bọ wa si ipinlẹ Kano tori aaye gba wọn daadaa nibẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCAN: Samson ni ọrọ awọn ajinigbe ti gba àpérò ní Naijiria

Ganduje sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu awọn oniroyin pe awọn ti n kọ ọgba nla nla fun awọn Darandaran ti awn si ti pe fun owo iranwọ latọdọ Banki Islam lati le pese okoojẹ fun awn maalu wọn.

Ṣaaju alaga ẹgbẹ NEF, Ọjọgbọn Ango Abdullahi ti sọ pe idi ti awọn fi ke si awọn Fulani Darandaran ki wọn dari pada si iha Ariwa waye latari ẹsun pe o le ma si abo fun ẹmi wọn tori ọrọ ti awọn gomina iha Guusu sọ.

Awọn Iroyin ti ẹ le nifẹ si

Lẹyin eyi lawọn Gomina ẹkun Guusu-Iwọ Oorun eyi to ko awọn ipinlẹ Yoruba pọ sọ pe ko sewu loko longẹ awọn ki awn Fulani to ba wa lagbegbe ma foya ati sa lọ.

Wọn ni tori awọn Gomina ipinlẹ mẹfẹfa ti n ṣe akitiyan lati rii pe abo to daju wa fun gbogbo eniyan lẹkun wọn nitori naa ki wn ma gb ohun ti ẹgbẹ awọn agba ẹkun Ariwa n sọ.