Ọjà Enugu dahoro tórí ókú ọ̀pọ̀ ẹyẹ igún tó balẹ̀

Aworan ẹyẹ igun Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Aworan ẹyẹ igun

Awọn oku ẹyẹ igunugun ti wọn ri kaakiri ilẹ lọja Eke-Ihe ni ijọba ibilẹ Awgu ti di ọrọ to n tan kalẹ laarin awọn araalu latari fidio kan to wa lori ẹrọ ayelujara lati ọjọ aiku.

Iroyin to tẹle eyi ni wi pe lẹyin ti wọn jẹ ẹran maalu ni awọn ẹyẹ igun naa fo ṣanlẹ ku.

Ẹwẹ, agbẹnusọ fun ile iṣẹ Ọlọpaa, Ebere Amaraizu ti wa fi ọrọ ranṣẹ fun awọn araalu pe ki wọn ma foya o.

Ile iṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Enugu bu ẹnu atẹ lu ọpọlọpọ ẹsun to n tan kalẹ ati eyi to sọ pe iṣẹ ọwọ awọn to n ji ẹranko pa lọna aitọ lo fa iku awọn ẹranko abiyẹ naa.

O ni ṣe ni awọn to ma n pa wọn yii ma n po nkan pọ mọ ẹran ti wọn ti pa silẹ ati igbẹ wọn lati fa oju awọn Igunugun mọra ki wọn lee wa jẹ.

Wọn ni bi wọn ba ti jẹ ẹ, ara a rẹ wọn, wọn a si gba ibẹ ku ki awọn to ji wọn pa le lọ ko wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionDele Momodu : Lẹ́yìn Buhari àti Atiku, èrò ọjà làwọn olùdíje yóòkù ní ìdìbò 2019

Ẹwẹ, iroyin naa sọ pe awọn ẹyẹ Igun kan to ko si panpẹ apopọ yii ja bọ si ọja ilu Enugu, awọn to maa n ko wọn ko si tete ri wọn ko kọ̀rọ̀ naa to di tọrọ̀ fọn kalẹ.

Ni ile iṣẹ Ọlopaa jẹ ko di mimọ pe iku wọn ko wa latọwọ ẹran kankan ti wọn pa fun jijẹ awọn eniyan bi ko ṣe iṣẹ ọwọ awọn ẹni ibi to fẹ da omi alafia ilu ru ni.

Kọmisana ni ki wọn ma jẹ ko di wọn lọwọ iṣẹ oojọ wọn ki wọn si jẹ araalu to n pa ofin mọ tori awọn ṣi n ṣe iwadii boya ẹran maalu kan ti wọn pa ti wọn si n ta lọja Eke-Ihe lo fa iku wọn.

Awọn Iroyin mii ti ẹ le nifẹ si