Police vs Shiite: Ẹ̀mí sùn níbi ìkọlù Shiite àti àwọn ọlọ́pàá l'Abuja

ina
Àkọlé àwòrán ọfọ ṣẹ lagbo ile akọroyin!

Precious Owolabi to n sinru ìlú pẹlu ileeṣẹ amohunmaworan Channels TV ti gbẹmi mi nibi ikọlu Shiite.

Iroyin ti ileeṣẹ iroyin Channels fi sita ṣalaye pe, ọdọmọkunrin yii fi ara gba ọta ibọn nibi ikọlu iwọde ẹgbẹ Shiite.

Wọn ni ibọn ọhun ba a nigba ti awọn agbofinro ati awọn oluwọde Shiite gbena woju ara wọn ni.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸ̀mí sùn níbi ìkọlù Shiite àti ọlọ́pàá

Omo ọdun mẹtalelogun naa to n sin ilẹ baba rẹ pẹlu ileeṣẹ Channels pada dagbere faye lataari ọgbẹ naa.

Awọn alaṣẹ ati oṣiṣẹ ileeṣẹ iroyin gbogbo lo ba Channels kẹdun ọfọ ọdọmoọkunrin Precious Owolabi yii.

Pe ki Olorun tẹẹ si afẹfẹ rere ni adura gbogbo awọn eeyan ni ileeṣẹ Channels.

Iroyin wo lo n jade nibi ikọlu Shiite ati awọn agbofinro:

Ẹgbẹ shiite sọ pe ọmọ ẹgbẹ awọn mọkanla lo gbẹmi mi ti ọpọ eeyan si fara pa nibi ikọlu to waye laarin ẹgbẹ naa atawọn ọlọpaa lọjọ Aje loluulu orilẹ-ede Naijiria, Abuja.

Ẹgbẹ naa n fẹhonu han nitori olori wọn to wa latimọle, Ibrahim Zakzaky, ohun ti wọn n beere fun ni pe ki ijọba fun un lominira.

Image copyright oTHER
Àkọlé àwòrán Ikọlu Shiite

Iroyin tilẹ sọ pe ọga ọlọpaa kan naa tẹri gbaṣọ nibi iṣẹlẹ ọhun ṣugbọn ile isẹ ọlọpaa ko tii fidii ọrọ naa mulẹ.

Àkọlé àwòrán Ilu Abuja

Ọkan lara awọn afẹhonu han sọ fun BBC pe o ti di eeyan bii mẹfa to ku ti oun ri nibi ija naa ṣugbọn ko tii si aridaju eyi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionDele Momodu : Lẹ́yìn Buhari àti Atiku, èrò ọjà làwọn olùdíje yóòkù ní ìdìbò 2019

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni wi pe awọn ọmọ ẹgbẹ ẹlẹsin musulumi Shiite ti wọn n pe ni Islamic Movement of Nigeria atawọn ọmọ ọlọpaa Naijiria wọya ija ni olu ilu orilẹ-ede yii, Abuja.

Gẹgẹ bi iroyin ti a gbọ ṣe sọ ọ, ọpọlọpọ lo ti fara pa yanayana ti ẹmi si ti lọ si i ṣugbọn awọn Ọlọpaa ko tii le sọ aridaju eyi.

Akọroyin BBC to wa ni ilu Abuja jabọ pe awọn ọlọpaa ni awọn ti n gbiyanju lati rọ ọwọ iṣẹlẹ naa.

Loju opo Twitter ile iṣẹ ọlọpaa, wọn ni oju awọn afẹhonu han naa gboro gan ṣugbọn awọn n ṣe iṣẹ awọn.

Ninu ọ̀rọ̀ ti alukoro ile iṣẹ ọlọpaa, DCP Frank Mba fi sita, wọn ni ki gbogbo ara ilu fi ara balẹ pe ohun gbogbo yoo rọlẹ.

Ṣaaju akoko yii ni awọn ọmọ ẹgbẹ Shiite ti n ja fun ki wọn tu adari ẹgbẹ wọn, Sheikh Ibrahim El-Zakzaky ti wọn ti fi si ahamọ lati ọdun 2015 silẹ.

Awọn Iroyin mii ti ẹ le nifẹ si