Senator Elisha Abbo: Ẹjọ́ gbogbo di ogúnjọ́ oṣù kẹjọ

Elisha Ishaku Abbo Image copyright @ElishaCliff

Ile ẹjọ Majisireeti kan niluu Abuja ti sun ẹjọ Sẹnetọ Elisha Abbo ti wọn fi ẹsun kan pe o lu obinrin nile itaja nkan iṣere ibalopọ siwaju di ogunjọ oṣu kẹjọ ọdun yii.

Akroyin BBC jabọ pe idi ti wọn fi tun sun un siwaju ni lati jẹ ki awọn ọlọpaa le pese gbogbo aridaju ti wọn nilo fun idajọ naa.

Lori ẹsun lilu eeyan lọna aitọ pẹlu aridaju ni wọn fi gbe sẹnetọ Elisha lọ siwaju ile ẹjọ.

ile iṣẹ ọlọpaa Naijiria lo bẹrẹ ipẹjọ yii lori sẹnetọ to n ṣoju ẹkun ariwa ipinlẹ Adamawa lẹyin ti fọnran kan jade to safihan bi o ti n lu obinrin kan ni ile itaja nkan iṣere ibalopọ lAbuja.

Bi o tilẹ jẹ pe sẹnetọ naa ti tọrọ aforiji fun iwa rẹ, awọn ọmọ Naijiria ni afi ki wọn fi jofin.

Abbo tọrọ aforojin yii pẹlu ikaanu nla, lasiko ipade akọroyin to se ni olu ile ẹgbẹ PDP to wa nilu Abuja.

Awọn Iroyin mii ti ẹ le nifẹ si