Ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo pàṣẹ fún àwọ̀n agbófinró láti mú àwọn fijilanté fulani l'Ondo

Kaadi idani vijilante kan Image copyright others

Ṣe ẹyin ti gbọ nipa fijilante fulani?

Bẹẹni, nibayii wọn ti wa ni ipinlẹ Ondo; ijọba ipinlẹ naa si ti gbe aṣẹ kalẹ pe gbogbo ọmọ ẹgbẹ fijilante naa ni ki awọn agbofin o fi panpẹ ofin mu ni kiakia.

Gẹgẹ bii kọmiṣọna feto iroyin nipinlẹ Ondo, Donald Ojo ṣe sọ, ijọba ko mọ pe iru ẹgbẹ bẹẹ wa nikalẹ ni ipinlẹ ọhun ki ogbontagi amofin kan ti orukọ rẹ n jẹ Kayode Ajulọ to ṣi aṣọ loju wọn.

Amofin Ajulọ la gbọ pe o fi aworan kaadi idanimọ wọn si ori ayelujara lẹyin to ni oun ṣe kongẹ wọn ni agbegbe Akoko ni ipinlẹ Ondo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Fulani Ilorin l'ọkọ mi'

Amofin Kayọde Ajulọ ti kọkọ ṣalaye pe lopin ọsẹ to kọja ni oun ṣe alabapade awọn darndaran fulani kan ti wọn ṣe apejuwe ara wọn gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ fijilante fulani ni agbegbe naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFulani Heardsmen: Afenifere ní àṣẹ tó bá wu àwọn àgbàgbà agbègbè àríwá Nàìjíríà ni

O ni ni tootọ ko si eyikeyi ninu wọn to dide ogun tabi wahala si oun ṣugbọn wọn duro si 'oju opopona marosẹ pẹlu ibọn lọwọ'

Gẹgẹ bi alaye rẹ, "awọn ẹṣọ alaabo to ba mi rin bi awọn eeyan ọhun pe kini iṣẹ wọn loju popo pẹlu ibọn lọwọ? wọn si dahun pe ọmọ ẹgbẹ fijilante Miyetti Allah lawọn atipe gbogbo awọn oṣiṣẹ alaabo agbegbe ọhun lo mọ awọn ti wọn si fi kaadi idanimọ wọn han."

Amọṣa, ijọba ipinlẹ Ondo ni awọn ko mọ eegun to n jẹ fijilante Miyetti Allah ni igboro ipinlẹ Ondo nitori naa, ki awọn agbofinro bẹrẹ si nii mu ẹnikẹni to ba n pe ara rẹ ni ọmọ ẹgbẹ naa ni wara-n-ṣeṣa.