5:30 p.m ni ojú mi déédé fọ́ níbi tí mo ti ń darí ọkọ̀ ni Ọrẹgun Ikẹja -LASTMA Yesufa
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

LASTMA Yesufa: Àwọn dókítà gbìyànjú lórí ojú mi ṣùgbọ́n...

LASTMA gbiyanju pupọ fun mi -Yesufa.

Ọrọ iyanu nla ni igbeyawo arakunrin Olawale Yesufa to jẹ oṣiṣẹ ajọ ẹṣọ oju popo nipinlẹ Eko, LASTMA.

Lẹyin igbeyawo to gba ori opo ayelujara kan ni BBC Yoruba lo wadii ijinlẹ ohun to sọ ọgbẹni yii di afọju ọsan gangan.

O mẹnuba ipa pataki ti ajọ LASTMA ko lati jẹ ki oun riran pada lẹyin iṣẹlẹ yii to ja si pabo.

Ogbẹni Yesufa Olawale ṣalaye fun BBC Yoruba bi oju rẹ ṣe deede ṣali riran mọ laisko to wa lẹnu iṣẹ ni Oregun ni Ikeja ni ipinlẹ Eko.

O sọrọ lori bi oun ṣe pade ololufẹ oun, Yesufa Adenikẹ lẹnu ikọni nipa igbe aye afọju ati awọn ipenija rẹ gbogbo.

Oṣiṣẹ LASTMA yii yombo ajọ LASTMA ati ohun gbogbo ti wọn ṣe fun un ki inu rẹ le dun lẹnu iṣẹ oojọ rẹ.