Shiite: Àwa kọ́ la yìnbọn pa ọ̀gá ọlọ́pàá àti akọ̀ròyìn

tarzomar 'yan Shi'a a Abuja Image copyright KOLA SULAIMON

Ẹgbẹ musulumi Shiite, Islamic Movement in Nigeria, ti sọ pe, awọn kọ lo ṣeku pa ọga ọlọpaa, Usman Musa ati akọroyin ileeṣẹ Channels.

Umar Usman ati Precious Owolabi ni wọn tẹri gbaṣọ ninu ikọlu ọlọpaa ati ẹgbẹ Shiite, nigba ti wọn n ṣe iwọde l'Abuja lọjọ Aje.

Aarẹ ẹgbẹ ọhun, Ibrahim Musa ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Iṣẹgun ṣalaye pe, ọta ibọn awọn ọlọpaa lo ba awọn mejeeji nitori awọn ẹgbẹ Shiite kii lo ibọn tabi ohun ija oloro kankan.

O ni ko ṣeeṣe ko jẹ pe awọn ọmọ ẹgbẹ Shiite to n ṣe iwọde lo yinbọn pa awọn mejeeji.

Aarẹ ẹgbẹ musulumi Shiite ni, ibanilorukọjẹ ni ọrọ ti ile iṣẹ ọlọpaa sọ pe Shiite lo ṣekupa ọga ọlọpaa Musa ati Owolabi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸ̀mí sùn níbi ìkọlù Shiite àti ọlọ́pàá

Ọgbẹni Musa ṣalaye pe, pẹlẹ kutu ni iwọde awọn n lọ ko to di pe awọn ọlọpaa da gbogbo rẹ ru.

Lakotan, ẹgbẹ Shiite kẹdun pẹlu awọn ẹbi awọn to ku ninu ikọlu ọjọ Aje papaajulọ ẹbi ọga ọlọpaa ati oniroyin to ṣagbako iku ojiji ninu iṣẹlẹ ọhun.

Ìdí ti a fi kọ̀ láti fi El-ZakZakky sílẹ̀ -Ileeṣẹ Aarẹ Buhari

Ìdí ti a fi kọ̀ láti fi El-ZakZakky sílẹ̀ gẹgẹ bi ilé ẹjọ ṣe paṣẹ rẹ - Ileeṣẹ Aarẹ.

Ogbẹni Femi Adesina to jẹ oludamọran fun aarẹ Mohammadu Buhari lori ọrọ iroyin ni kii ṣe pe ijọba fẹ tako aṣẹ ofin ile ẹjọ rara.

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Afi ki wọn tu Zakzaky silẹ ni ariwo ti awọn Shiite n pa

O ni ijọba Buhari gbà pé o ni idi ti Adajọ Abubakar Malami (SAN) N3.5 mílíọ̀nù lórí El-Zakzaky, kíni àwọn ọmọ Nàìjíríà ń sọ?ṣe fi paṣẹ pe ki wọn tu olori ẹsin Islam Shiite silẹỌ̀pọ̀ èèyàn farapa nínú ìwọ́de Shiite.

Femi Adesina ni nitootọ ni o jẹ pe Adajọ agba ni Naijiria to paṣẹ itusilẹ El Zakzakky ati aya rẹ kuro ninu tubu ṣe eyi gẹgẹ bii agbara ofin ni.

O ni koko pataki ni pe ti adajọ ba dajọ, aaye wa lati pe idajọ naa ninu ẹjọ kotẹmilọrun bi o ti yẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionHuman Rights day: Aṣíwájú ajàfẹ́tọ̀ọ́ ní Àìbọ̀wọ̀ fẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn ló ń fa wàhálà ètò àbò

Femi Adesina ni kete ti wọn ba ti ni ki eeyan gba oniduro ninu ẹjọ ṣugbọn ti igbẹjọ kotẹmilọrun ba dide ni ofin ti faye gba pe ki wọn ṣi fi ẹni naa si ahamọ titi yoo fi yanju.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionShiite: Tinúbú, bá Buhari sọ̀rọ̀ kó tú ZakZaky sílẹ̀ kó tó pẹ́ jù

O ni oun ko mọ ofin ni kikun ṣugbọn nkan kan ti o da oun loju ninu ifọrọwerọ naa ni pe ijọba ti gbe ẹjọ kotẹmilọrun lọ sile ẹjọ agba ni ipinlẹ Kaduna.

Femi Adesina parọwa fawọn olujọsin Shiite pe ki wọn ni suuru nitori ọjọ Aje to m bọ nigbẹjọ yoo waye nile ẹjọ ni Kaduna.

Agbẹnusọ fun aarẹ Buhari gboriyin fawọn agbofinro Naijiria pe wọn gbiyanju lasiko iwọde awọn ijọ Shiite to wyae ni Abuja.

Iwọde yii lo mu ẹmi opolopo eeyna lọ ati ti agunbanirọ Channels kan ati ọga agba ọlọpaa kan.

O ni kani awọn ọlọpaa sọ̀kò ẹyẹ ihuwasi awọn Shiite nibi iwọde yẹn nipa yinyin ibọn ni, ọpọ ẹmi ko ba tun sọnu sii.

Femi Adesina ni ẹmi ọga ọlọpaa to sọnu sinu iṣẹlẹ iwọde yii to eyi to n gba ẹbọ lọwọ awọn oluwọde ṣugbọn oun ki awọn agbofinro fun gbigba alaafia laaye lai nii fiṣe ohun gbogbo to ṣẹlẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionDele Momodu : Lẹ́yìn Buhari àti Atiku, èrò ọjà làwọn olùdíje yóòkù ní ìdìbò 2019