Báwo ni Yorùbá ṣe ń kí ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí ọmọ tuntun?
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Yoruba Culture: àṣà ìkínni ṣe pàtàkì nílẹ̀ Oodua

Ayọ abara tíntín ni Yoruba ka ọmọ tuntun sí.

Ẹbun ọfẹ ni ọmọ jẹ, ìran Yoruba si gbà pé ẹni tó ba wu Aṣẹda ni o le fun ni ọmọ lasiko to wu u.

Ni kete ti abiyamọ ba ti bi ìkókó si ilé ayé ni ẹbi, ara ati ojulumọ a ti wa maa ki wọn ku oriire alejo tuntun ni ọọdẹ wọn.

Nitori ki awọn ọmọde ati ọdọ Yoruba le ranti pataki ikinni nilẹ Oodua ni BBC Yoruba ṣe jade lọ beere bi a ti n ki ọlọmọ lọwọ awọn eniyan.

Oriṣii ikinni to wọpọ bii:

Ẹ ku ewu ọmo tuntun; Ẹ ku ọwọ lomi; Ayọ naa a kari; Olorun a wo o; Olorun a da a si, E ku ajabọ, O maa ni ọ̀wọ́ rere lẹ́yìn ati bẹẹ bẹẹ lọ ni a gbọ.

Ewu nla ni oṣu mẹsan an ti obinrin fi diwọ́-disẹ̀ sínú fi gbe oyun ikoko naa ki Edumare to sọ ọ kalẹ layọ.

Awọn eniyan ṣalaye kikun lori ohun to ṣokunfa awọn adura ati ikinni fun ọlọmọ tuntun daadaa.