Nigeria ministers: Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àwọn obìnrin méje ti Buhari forúkọ wọn ránṣẹ

Image copyright others
Àkọlé àwòrán Wo awọn oju obinrin ti wọn le di minista lẹyin ayẹwo ile igbimọ aṣofin to n lọ lọwọ

Lọjọ Iṣẹgun ni Aarẹ Mohammadu Buhari fi orukọ awọn minista mẹtalelogoji ranṣẹ sile igbimọ aṣofin ni Abuja.

Ninu orukọ awọn mẹtalelogoji ti Buhari fẹ ki ile igbimọ ṣe ayẹwo fun, o yani lẹnu pe obinrin meje pere ni o wa ninu orukọ mẹtalelogoji naa.

Eyi ja si pe ida mẹrindinlogun ninu ọgọrun un pere ni abo to maa ba ijọba Buhari ṣiṣẹ ni saa keji ijọba rẹ yii.

Bẹẹ naa lo ṣe jẹ pe obinrin mẹfa pere naa lo ṣe minista pẹlu aarẹ Buhari ni saa iṣejọba rẹ akọkọ ninu awọn minista mẹrindinlogoji to yan nigba naa.

Eyi ja si pe ida mẹrindinlogun naa ni o tun n tun fẹ lo lasiko yii.

Awọn obinrin meje ti orukọ wọn pada wọnu iwe awọn tile igbimọ n ṣayẹwo fun ni:

1) Pauline Tallen:

Labẹ ijọba Oluṣẹgun Obasanjọ, Baba Iyabọ ni arabinrin Pauline ti kọkọ ṣiṣẹ pọ.

O jẹ ọmọ ọgọta ọdun oloṣelu lati ipinlẹ Plateau.

Image copyright @Tallen
Àkọlé àwòrán Pauline ni obinrin akọkọ to jẹ igbakeji gomina ni ariwa Naijiria

Pauline lo ṣe minista abẹle fun ileeṣẹ ijọba to n ri si imọ sayẹnsi ati imọ ẹrọ lọdun 2007.

Oun ni igbakeji gomina ipinlẹ Plateau ko to o tun dije dupo gomina ipinlẹ naa lọdun 2011 ki Jonah Jang to jawe olubori.

O ka ẹkọ nipa imọ ẹda ni fasiti Jos. O bẹrẹ oṣelu rẹ pẹlu ẹgbẹ PDP ko to ṣi lọ si ẹgbẹ oṣelu APC

2) Mariam Katagun:

Mariam Katagun ti jẹ aṣoju Naijiria si ajọ iṣokan agbaye ni eto ẹkọ ati àṣà UNESCO.

Ipo yii lo di mu titi di oṣu kẹfa, ọdun 2009.

Oun ni igbakeji oludari nileeṣẹ ijọba to n mojuto eto ẹkọ ko to lọ gba iṣẹ akọwe agba ni UNESCO lọdun 2001.

Fasiti Ahmadu Bello lo ti kẹkọọ gboye ko to lọ gba iṣẹ ọkan lara awọn igbimọ Commonwealth of Learning.

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Obinrin ti setan lati ba Aare Buhari sise ni saa yii.

3) Sadiya Farouq:

Arabinrin Sadiya ti figba kan jẹ kọmiṣonna ijọba apapọ fun ajọ to n mojuto ọrọ awọn aṣatipo.

Lọdun 2011 si 2013 lo fi ṣe akapo ẹgbẹ oṣelu Congress for Progressive Change (CPC) ti aarẹ Buhari dije ninu rẹ fun ọpọlọpọ ọdun ko to darapọ mọ APC.

Bakan naa lo tun ba aarẹ Buhari ṣiṣẹ ninu ẹgbẹ CPC gẹgẹ bi akapo gbogboogbo lọdun 2013 si 2014.

Image copyright @Sadiya
Àkọlé àwòrán O je akapo egbe oselu CPC ti o koko gbe Aare Buhari jade

4) Gbemisola Saraki:

Gbemisola Saraki jẹ ọkan pataki lara awọn ti oju gbogbo n wo ninu awọn ti Aarẹ Buhari forukọ wọn ranṣe sile igbimọ aṣofin.

Gbemi jẹ ọmọ bibi inu agba ọjẹ oloṣelu Oluṣọla Saraki to n dari iṣelu ipinlẹ Kwara fun ọpọlọpọ ọdun ko to di oloogbe.

Oun naa ni aburo aarẹ ile igbimọ aṣofin agba to kogba wọle laipẹ yii, iyẹn Bukọla Saraki.

Lọdun 1999 ni wọn yan an sile igbimọ lati ṣoju ẹkun Asa / Ilorin nipinlẹ Kwara.

Image copyright @Gbemi
Àkọlé àwòrán Opo gba pe Gbemi ṣiṣẹ lodi si iyansipo ẹgbọn rẹ titi o fi togẹ ni Kwara

Gbemi jẹ ọmọ ọdun mẹrinlelaadọta to kẹkọ gboye nipa imọ eto ọrọ aje ni fasiti Sussex nilu Ọba.

O jẹ senetọ ẹkun aarin gbungbun Kwara titi di ọdun 2011 nigba to dije dupo gomina ipinlẹ Kwara lẹyin ti Bukola Saraki ẹgbọn rẹ fipo naa silẹ.

O pada lọ darapo mọ ẹgbẹ oṣelu APC lọdun 2015 ni eyi ti awọn neiyan gba pe o ṣiṣẹ lodi si ẹgbọn rẹ ninu idibo to kọja lọ to fi to gẹ ni Kwara.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOkunrounmu: Ijọba Buhari jẹ ijiya Ọlọrun fun Naijiria

5) Zainab Ahmed:

Odu ni ninu iṣẹ minista kii ṣe aimọ fun oloko.

Zainab ni o jẹ minista abẹle fun eto iṣuna ati ilana aatẹle fun ijọba apapọ lọdun 2015.

Oun lo pada di minista fun inawo ni Naijiria lọdun 2018 nigba ti o gba iṣẹ lọwọ Kẹmi Adeọṣun.

Fasiti Ahmadu Bello ni Zaria lo ti kọ ẹkọ nipa iṣiro owo ko to gba oye keji ni Fasiti Olabisi Onabanjọ ni ipinlẹ Ogun.

Image copyright @Zainab
Àkọlé àwòrán Zainab ni o jẹ minista abẹle fun eto iṣuna ati ilana aatẹle fun ijọba apapọ lọdun 2015.

Zainab ti jẹ akọwe agba fun Nigeria Extractive Industries Transparency Initiative tẹlẹ.

Omo bibi Yahaya Hamza to jẹ baba to tọ Nasir El Rufai dagba to jẹ gomina ipinlẹ Kaduna.

6) Sharon Ikeazor:

Sharon Ikeazor jẹ akọwe agba fun ajọ to n ri si owo ifẹyinti awọn oṣiṣẹ, iyẹn, Pension Transitional Arrangement Directorate (PTAD).

Oun ni olori awọn obinrin ninu ẹgbẹ oṣelu CPC ti aarẹ Buhari ti kọkọ dije ko too darapọ mo ẹgbẹ oṣelu APC.

Bakan naa lo ṣiṣẹ bii olori awọn obinrin fidiẹ fun ẹgbe APC lẹyin ti wọn darapọ lọdun 2014.

Wọn pada yan an sinu awọn ọmọ igbimọ alamojuto ẹgbẹ APC ti aarẹ Buhari ba wọle lati 2015.

Image copyright @ikeazor
Àkọlé àwòrán Wọn pada yan an sinu awọn ọmọ igbimọ alamojuto ẹgbẹ APC ti aarẹ Buhari ba wọle lati 2015.

7) Ramatu Tijjani:

Ramatu Tijjani jẹ ọmọ ọdun mọkandinlaadọta.

Oun ni olori awọn obinrin ninu ẹgbẹ oṣelu APC ti aarẹ Buahri lo fi n tukọ Naijiria bayii.

O kẹkọọ nipa aato ile kikọ ni agbegbe ni Fasiti Ahmadu Bello ni Zaria.

Oun ni igbakeji alaga obinrin akọkọ fun aarin gbungubn ariwa Naijiria.

Oun ni olori awọn obinrin ninu ẹgbẹ oṣelu ANPP ti Buhari ba dije tẹlẹ.

Lọdun 2014 lo di olori awọn obinrin ni ẹgbẹ oṣelu APC.

Image copyright Others
Àkọlé àwòrán Obinrin ti to gabngba sun lọyẹ ninu iṣelu Naijiria

Lẹyin ti ile igbimọ aṣofin ba ti pari ayẹwo ti wọn bẹrẹ loni ni a maa mọ awọn to ba wọle gẹgẹ bii minista ati ipo ti wọn maa di mu.