Ekiti: Ọmọ ọdun méje di ọ̀rẹ́ Gómìnà Ekiti

Oríṣun àwòrán, @ekitistategov
Awọn Yoruba maa n ni b'eegun ẹni ba mọọ jo, ori a maa ya atọkun.
Ati Gomina Kayode Fayemi, ati obi Daniel Olutope to fi mọ awọn olukọ rẹ ni ori wọn wu si iṣe-daradara rẹ.
Bi itan ọrẹ laarin ọmọ ọdun meje, Daniel ati gomina ipinlẹ Ekiti ṣe bẹrẹ rèé.
Oríṣun àwòrán, @ekitistategov
Sababi lo kuku gbe wọn rina ko ra wọn lọjọ keje, oṣu keje, ọdun yii nigba ti gomina Kayode Fayemi lọ ba awọn ọmọ ile iwe alakọbẹrẹ jẹun ọsan pọ.
Ni St. Michael's Primary School ti ilu Ado Ekiti lọjọ naa lọhun, bi Daniel ṣe ba gomina sọrọ ri bii ọmọ ọlọgbọn ni to bẹẹ ti gomina beere boya o lee wa ki oun sile.
Daniel gba lati wa a lọ sile; o si ṣeleri pe iya oun yoo mu oun wa.
Ẹwẹ, arabinrin Oluwatoyin Olutope Adaramodu to jẹ iya Daniel ko kọkọ gbagbọ nigba ti ọmọ dele royin pe gomina fẹ di ọrẹ oun.
Lẹyin oṣu diẹ ni gomina wa ran awọn oluranlọwọ rẹ lati tun lọ bẹ Daniel wo nile iwe ki wọn si mu u wa si ọfiisi oun.
Iya Daniel sin ọmọ rẹ lọ ati olukọ rẹ, arabinrin Dupe Adeosun si ọfiisi gomina eleyi si wa di anfani banta banta fun Daniel lati sare jẹ gomina fun akoko ranpẹ.
Oríṣun àwòrán, @ekitistategov
Ikinni ṣe pataki ninu aṣa ati iṣe Yoruba
"Ṣé o ránti mi báyìí, emi arakunrin to n gbe lori oke giga? Ọmọwe Fayemi beere eyi lọwọ Daniel to si ni "bẹẹ ni, mo ranti".
Ni gomina ba mu u lọ si ibi tabili rẹ to si gbe e joko sori aga gomina. O bọ ọ lọwọ o ni "Kẹẹ pẹ ọlọla julọ".
'Jollof, Iyan, Asaro, Ewa Alagbado kìí wọ́n n'ílé oúnjẹ wá ní Egypt'
Gomina Fayemi beere pe njẹ Daniel yoo nifẹ lati di gomina bi o ba dagba, Daniel si gba pe bẹẹ, ni gomina wa gba a niyanju lati tẹra mọ ẹkọ rẹ ki ala rẹ le e di mimuṣẹ.
Idunnu ko ṣee fi pamọ fun iya Daniel to ni ibẹwo yii jẹ ijọloju fun oun ati pe inu oun dun lati ri ọmọ rẹ lori aga gomina.
O ni eyi jẹ ami pe ọmọ oun lee di gomina lọla bii Ọmọwe Kayode Fayemi.
Oríṣun àwòrán, @ekitistategov
O rọjo adura aṣeyọri fun gomina o si dupẹ lọwọ rẹ fun ọwọ ifẹ to na si ọmọ rẹ.
Bayii ni Daniel Olutope ti ṣe gomina ipinlẹ Ekitit fun wakati meloo kan.
Awọn Iroyin mii ti ẹ le nifẹ sii
- Barrister ló sọ mí di èèyàn ńlá - Ayinla Kollington
- Ìtàn tó wà nídi òwe ‘Sebótimọ Ẹlẹ́wà Sàpọ́n’
- Ìtàn tó rọ̀ mọ́ òwe ‘aṣọ kò bá Ọ́mọ́yẹ mọ́...’ rèé
- Afọnja, ẹni tó finú wénú ní Ilọrin, àmọ́ tó jẹ iwọ
- Ẹfunsetan Aniwura, obìnrin tó ju ọkùnrin lọ
- Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn, Aláàfin obìnrin àkọ́kọ́ rèé, tó ní nǹkan ọkùnrin