Leah Sharibu: Mo gbàgbọ́ pé ọmọ mi ṣì wà láàyè - Nathan Sharibu

Leah Sharibu Image copyright OTHER
Àkọlé àwòrán Leah Sharibu

"O da mi loju pe ọmọ mi ko ku, o ṣi wa laaye".

Baba Leah Sharibu ti fohun sita pe oun o gbagbọ rara ninu awuyewuye ti awọn kan n gbe kiri pe ọmọ oun ti ku.

Sharibu Nathan sọ fun ikọ̀ BBC pe oun ṣi nigbagbọ pe aaye ni ọmọ oun wa.

Ọkan lara awọn akẹkọbinrin ile iwe girama Dapchi ni Leah Sharibu ti ikọ Boko Haram jí gbé lọ ni ipinlẹ̀ Yobe ni Ọjọ Kọkandinlogun, Oṣu Keji ọdun 2018.

"Nipa iroyin to n tan kalẹ, mo ro pe irọ ni gbogbo wọn n pa. Bi o tilẹ jẹ pe emi naa ri i ka lori ayelujara, mo gbagbọ pe o wa laaye".

Àkọlé àwòrán Àwọn oṣìṣẹ́ ìrànwọ́ tí wọ́n jí gbé

Ọgbẹni Sharibu mẹnu le ọrọ yii lẹyin ti awọn ọmọ Naijiria tu sori ayelujara lati fesi si fọnran kan ninu eyi ti ọkan lara awọn oṣiṣẹ iranwọ ti ikọ Boko Haram ji gbe laipẹ yii sọ.

Nibi ti awọn oṣiṣẹ iranwọ ti wọn ji gbe naa n rawọ ẹbẹ si ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kristi, CAN ati ajọ to n ja lodi si ebi (Action against Hunger) lati wa tu awọn silẹ kawọn ẹṣin-o-kọku to ji wọn gbe to pa wọn bii ti Leah ati Alice.

Grace Taku to sọ ọrọ yii ko sọ pato boya Leah Sharibu tabi Leah mii lo n sọ ṣugbọn kete ni awọn eeyan bẹrẹ si ni tan an kalẹ pe Leah Sharibu lo n sọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKayeefi: Facebook ni Wolii Arole Jesu fi tàn an wọ agbo, orí rẹ̀ ni wọ́n fi s'owó

Nipa igba ti wọn gburo rẹ gbẹyin, baba rẹ sọ fun BBC pe nkan bii ọdun to kọja ni awọn gburo rẹ gbẹyin ti wọn ko si tii gbọ ohunkohun titi doni.

"Ojoojumọ ni ijọba apapọ n ṣeleri pe awọn yoo wa a ri, awọn n duna dura pẹlu awọn to ji i gbe, ṣugbọn a ko tii gbọ nkankan titi doni".

"Koda aarẹ funra rẹ pe iyawo mi lori ẹrọ ibanisọrọ ninu oṣu kẹwaa ọdun to kọja to si ṣeleri lati ṣa ipa rẹ ki ọmọ wọn pada wale lalafia".

O ni "ṣebi o ṣaa ni ki minisita mẹta wa si ile mi lati tu wa ninu ati fi aridaju han wa pe wọn yoo wa ọmọ wa ri ṣugbn lẹyin naa, lati oṣu kẹwa, ko sẹni to wa tabi kan si mi".

Sharibu Nathan ni ọrọ naa ba ni ninu jẹ gan ṣugbọn awọn fi gbogbo rẹ le Ọlọrun lọwọ.

"A fi gbogbo rẹ le Ọlọrun lọwọ a si n reti idajọ Ọlọrun".

Àkọlé àwòrán Ìyá Leah Sharibu

Ẹwẹ, oluranlọwọ pataki fun aarẹ lori ọrọ to kan araalu, Garba Shehu ni ifọrọwerọ ti n lọ lori bi wọn yoo ṣe tu gbogbo awọn to wa ni igbekun Boko Haram silẹ.

Ọgbẹni Shehu ko sọ boya Leah Sharibu wa laye aki ko si ninu atẹjade tirẹ ṣugbọn o ni oun ti fi ọrọ naa to ọfiisi aarẹ leti wọn yoo si gbe igbesẹ.

Awọn Iroyin mii ti ẹ le nifẹ sii