Jiti Ogunye: Ọjà òkùnkùn ni àyẹ̀wò Minisita ní Ilé Asòfin

Jiti Ogunye
Àkọlé àwòrán,

Awuyewuye ti jẹyo lori bi awọn Asofin Agba se kọ lati se ifọrọwanilẹnuwo lẹkunrẹrẹ fun awọn Minisita ti Aarẹ Buhari fi sọwọ si Ile Asofin Agba.

Ajafẹtọ ọmọniyan ati agbẹjọro, Jiti Ogunye ti bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu iṣesi awọn aṣofin to kọ lati se ifọrọwanilẹnuwo fun awọn minisita ti Aarẹ Buhari fi sọwọ si Ile Igbimọ Asofin.

Ogunye lasiko to n ba BBC sọrọ ni ọja okunkun ati ọja ẹtan ni Ile Igbimọ Asofin ati ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari n ṣe.

O ni ko ba ofin mu ki awọn minisita naa ma mọ ibi ti wọn fẹ yan wọn si, bẹẹ si ni awọn asofin naa ko fi ọrọ wa wọn lẹnu wo, nitori wọn ti wa ni ipo isejọba tẹlẹri.

Àkọlé fídíò,

Jiti Ogunye: Ìjọba àkóbá lológun gbé kalẹ̀ ni 1999

Agbẹjọro Jiti Ogunye ni iyalẹnu ni wi pe awọn ti wọn dibo yan ko ṣe ifẹ awọn ara ilu, wi pe ni ṣe ni ijọba n tan ara ilu jẹ.

Àkọlé fídíò,

Kayeefi: Facebook ni Wolii Arole Jesu fi tàn an wọ agbo, orí rẹ̀ ni wọ́n fi s'owó

Ogunye ni awọn aṣofin kuna ninu isẹ wọn, bakan naa ni awọn ti wọn yan si ipo naa ko le e se ohun to tọ, nitori wọn ko loye lbi ti wọn ti fẹ ṣe iṣẹ naa.

Ajafẹtọ ọmọniyan naa wa gba awọn ara ilu ni imọran lati ma a yan awọn ti o le e gbọran si wọn lẹnu, ti o si le e ṣe ifẹ awọn ara ilu.