Ojú òṣìṣẹ́-fẹ̀yìntì Naijiria ń rí tó!
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Nigeria Pensioners: Wàhálà àyẹ̀wò iwé ìfẹyinti yì ti pọ̀jù

Ara pupọ ninu wọn lo ti di ara agba ti nkan ko rọrun fun mọ.

Bi ojumọ ti n mọ ni eeyan n dagba ti ara n darugbo sii.

Bẹẹ, arugbo ṣe oge ri, akisa lo igba ri, oṣiṣẹ to ja fafa lẹnu iṣẹ loni ni yoo di oṣiṣẹ-fẹyinti lọla.

BBC Yorùbá jáde lọ fọrọ wa awọn oṣiṣẹ-fẹyinti ti ijọba n ṣe ayẹwo fun lẹnuwo lori ohun ti o n ṣẹlẹ nibi ayẹwo iwe wọn naa.

Oriṣiriṣi ailera lo ti de ba awọn oṣiṣẹ fẹyinti wọnyi ti ko fi jẹ ki eto igbesẹ ijọba rọrun fun wọn rara.

Ọpọ lo n tẹ ọ̀pá, ti awọn miran wa lori aga to n gbe alaisan kiri, ti ọpọ ko tilẹ riran mọ.

Awọn arugbo naa parọwa fun ijọba lati wo ilana miran ti yoo mu ki iṣẹ ayẹwo ti wọn n ṣe rọrun fun awọn sii lasiko yii.

Wọn ni ero ti pọ ju ti ko jẹ ki iṣẹ ayẹwo naa ya ti o fi n ga wọn lara.

Ijọba ni o di dandan lati maa ṣe ayẹwo " Mo ṣi wa láyé" fawọn oṣiṣẹ fẹyinti loorekoore ki wọn le mọ ohun to yẹ ni ṣiṣẹ fun wọn.