Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdí tí àwa Shiite fí ń fẹ̀hónúhàn ní Abuja -Zakariya
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Shiite: Ẹ̀mí àti ara wa kọ ohun tí ìjọba ń ṣe sìwa láti 2015

O lé ni ẹgbẹrun kan ninu wa ni Islamic Movement of Nigeria.

Orọ awọn ẹlẹsin Shiite ti di nkan miran lọwọ ni Naijiria lasiko yii.

Lati ọdun 2015 ti ijọba ti fi El Zakzakky to jẹ olori Islamic Movement of Nigeria si atimọle ni oriṣiiriṣii nkan ti n ṣẹlẹ.

Opọlọpọ ẹmi ati dukia awọn eeyan lo ti ba iṣẹlẹ iwọde awọn Shiite rin ni Naijiria.

Ijọba Naijiria n sọ pe awọn n wa alaafia ni. Èmi kò ní kí Shiite má ṣe ẹ̀sìn won o -Muhammadu Buhari

Bẹẹ lawọn Shiite naa pariwo pe awọn ko fẹ wahala ju ki ijọba ṣe ohun to yẹ fun awọn lọ.

BBC Yoruba jade lọ ṣe ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ọkan pataki lara awọn ọmọ ijọ ẹlẹsin Shiite, Zaynab Zakariyah lori ohun to n ṣẹlẹ gangan.

Oni ọjọ Aje ni igbẹjọ laarin Shiite ati ijọba yẹ ko tẹsiwaju ni Kaduna.

Zaynab ṣalaye ni kikun lori bi ọrọ yii ṣe bẹrẹ nitori ẹṣẹ kii deede ṣẹ lai nidi ni.

O fẹsun kan ijọba pe wọn pa ọmọ El Zakzakky mẹta ati awọn ọmọ Shiite to le ni ẹgbẹrun kan ni eyi to ṣokunfa iwọde kotẹmilọrun yii.

Zaynab ni "Ẹ kuro lọna mo fẹ kọja; ero pọ a ko le ya lọna' ni o kọkọ bi ọrọ atimọle El Zakzakky yii.

Eto ayajọ ọjọ ibi Anọbi Mohammed (SAW) ni a n ṣe to bi wahala ki wọn wa pa awọn eeyan wa ni Mọsalasi.

Sugbọn ohun ti IMN n fẹ ni ki ijọba fi olori awọn sile ati aya rẹ fun itọju nilẹ okeere.